7. Wọ́n gbé Àpótí Majẹmu náà jáde láti ilé Abinadabu, wọ́n gbé e lé orí kẹ̀kẹ́ titun. Usa ati Ahio sì ń wa kẹ̀kẹ́ náà.
8. Dafidi ati àwọn eniyan ń fi tagbára-tagbára jó níwájú Ọlọrun, pẹlu orin ati àwọn ohun èlò orin: dùùrù, hapu, ìlù, Kimbali ati fèrè.
9. Bí wọ́n ti dé ibi ìpakà Kidoni, àwọn mààlúù tí wọn ń fa kẹ̀kẹ́ náà kọsẹ̀, Usa bá di Àpótí Majẹmu náà mú kí ó má baà ṣubú.
10. Ṣugbọn inú bí Ọlọrun sí Usa, ó sì lù ú pa, nítorí pé ó fi ọwọ́ kan Àpótí Majẹmu, ó sì kú níwájú Ọlọrun.
11. Inú bí Dafidi nítorí pé Ọlọrun lu Usa pa, láti ọjọ́ náà ni a ti ń pe ibẹ̀ ní Peresi Usa títí di òní.
12. Ẹ̀rù Ọlọrun ba Dafidi ní ọjọ́ náà, ó ní, “Báwo ni mo ṣe lè gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun sọ́dọ̀?”
13. Nítorí náà, Dafidi kò gbé Àpótí Majẹmu sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi, kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbé e yà sí ilé Obedi Edomu, ará Giti.
14. Àpótí Majẹmu Ọlọrun náà wà ní ilé Obedi Edomu yìí fún oṣù mẹta, OLUWA sì bukun ilé Obedi Edomu ati gbogbo ohun tí ó ní.