Kọrinti Keji 6:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀, à ń bẹ̀ yín pé kí ẹ má ṣe jẹ́ kí gbígbà tí ẹ gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jẹ́ lásán.

2. Nítorí Ọlọrun sọ pé,“Mo gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ nígbà tí o bá ojurere mi pàdé;mo ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọjọ́ ìgbàlà.”Ìsinsìnyìí ni àkókò ojurere Ọlọrun. Òní ni ọjọ́ ìgbàlà.

3. A kò fi ohun ìkọsẹ̀ kankan siwaju ẹnikẹ́ni, kí àwọn eniyan má baà rí wí sí iṣẹ́ wa.

4. Ṣugbọn ninu gbogbo nǹkan, à ń fi ara wa sípò àyẹ́sí gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ Ọlọrun. A ti fara da ọpọlọpọ nǹkan ní àkókò inúnibíni, ninu ìdààmú, ati ninu ìṣòro;

5. nígbà tí wọ́n nà wá ati nígbà tí a wà lẹ́wọ̀n, ní àkókò ìrúkèrúdò ati ní àkókò tí iṣẹ́ wọ̀ wá lọ́rùn, tí à ń pa ebi mọ́nú.

6. À ń ṣiṣẹ́ pẹlu ọkàn kan; pẹlu ọgbọ́n ati sùúrù, pẹlu inú rere ati ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, pẹlu ìfẹ́ tí kò lẹ́tàn.

7. À ń ṣe iṣẹ́ wa pẹlu òtítọ́ inú ati agbára Ọlọrun. A mú ohun ìjà òdodo lọ́wọ́ ọ̀tún ati lọ́wọ́ òsì.

8. Bí a ti ń gba ọlá, bẹ́ẹ̀ ni à ń gba ìtìjú. Bí a ti ń gba èébú, bẹ́ẹ̀ ni à ń gba ìyìn. Àwọn ẹlòmíràn kà wá sí ẹlẹ́tàn, bẹ́ẹ̀ sì ni olóòótọ́ ni wá.

9. Ìwà wa kò yé àwọn eniyan, sibẹ gbogbo eniyan ni ó mọ̀ wá. A dàbí ẹni tí ń kú lọ, sibẹ a tún wà láàyè. A ti ní ìrírí ìtọ́ni pẹlu ìjìyà, sibẹ ìjìyà yìí kò pa wá.

10. A ní ìrírí ìbànújẹ́ nígbà gbogbo, sibẹ à ń yọ̀. A jẹ́ aláìní, sibẹ a ti sọ ọpọlọpọ di ọlọ́rọ̀. A dàbí àwọn tí kò ní nǹkankan, sibẹ a ní ohun gbogbo.

11. A ti sọ òtítọ́ inú wa fun yín, ẹ̀yin ará Kọrinti. Ọkàn wa ṣípayá si yín.

12. Kò sí ohun kan ní ọkàn wa si yín. Bí ohun kan bá wà, a jẹ́ pé ní ọkàn tiyín ni.

13. Mò ń ba yín sọ̀rọ̀ bí ọmọ. Ohun tí ó yẹ yín ni pé kí ẹ ṣí ọkàn yín payá sí wa.

14. Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ àwọn alaigbagbọ. Nítorí ìrẹ́pọ̀ wo ni ó wà láàrin ìwà òdodo ati aiṣododo? Tabi, kí ni ó pa ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn pọ̀?

15. Báwo ni Kristi ti ṣe lè fi ohùn ṣọ̀kan pẹlu Èṣù? Kí ni ìbá pa onigbagbọ ati alaigbagbọ pọ̀?

Kọrinti Keji 6