3. Ìdí tí mo fi kọ ìwé tí mo kọ si yín nìyí, nítorí n kò fẹ́ wá kí n tún ní ìbànújẹ́ láti ọ̀dọ̀ ẹ̀yin tí ó yẹ kí ẹ fún mi láyọ̀. Ó dá mi lójú pé bí mo bá ń yọ̀, inú gbogbo yín ni yóo máa dùn.
4. Nítorí pẹlu ọpọlọpọ ìdààmú ati ọkàn wúwo ni mo fi kọ ọ́, kì í ṣe pé kí ó lè bà yín lọ́kàn jẹ́ ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé ìfẹ́ tí mo ní si yín pọ̀ pupọ.
5. Ní ti ẹni tí ó dá ìbànújẹ́ yìí sílẹ̀, èmi kọ́ ni ó bà ninu jẹ́ rárá. Láì tan ọ̀rọ̀ náà lọ títí, bí ó ti wù kí ó mọ, gbogbo yín ni ó bà ninu jẹ́.
6. Ìyà tí ọpọlọpọ ninu yín ti fi jẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti tó.
7. Kí ẹ wá dáríjì í. Kí ẹ fún un ní ìwúrí. Bí ìbànújẹ́ bá tún pọ̀ lápọ̀jù kí ó má baà wó irú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀.
8. Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ jẹ́ kí ó mọ̀ pé ẹ fẹ́ràn òun.
9. Ìdí tí mo fi kọ ìwé sí yín ni láti fi dán yín wò, kí n lè mọ̀ bí ẹ bá ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu ninu ohun gbogbo.
10. Bí ẹ bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi náà dáríjì í. Nítorí tí mo bá ti dáríjì eniyan, (bí nǹkankan bá fi ìgbà kan wà tí mo fi níláti dáríjì ẹnikẹ́ni), mo ṣe é nítorí tiyín níwájú Kristi.
11. Nítorí a kò gbọdọ̀ gba Èṣù láyè láti lò wá, nítorí a kò ṣàì mọ ète rẹ̀.
12. Nígbà tí mo dé Tiroasi láti waasu ìyìn rere Kristi, Oluwa ṣínà fún mi láti ṣiṣẹ́.
13. Ṣugbọn ọkàn mi kò balẹ̀ nígbà tí n kò rí Titu arakunrin mi níbẹ̀. Mo bá dágbére fún àwọn eniyan níbẹ̀, mo lọ sí Masedonia.
14. Ṣugbọn ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó jẹ́ kí á lè wà ninu àjọyọ̀ ìṣẹ́gun tí Kristi ṣẹgun, nígbà gbogbo. Ọlọrun náà ni ó tún ń mú kí ìmọ̀ rẹ̀ tí ń jáde láti ara wa máa gba gbogbo ilẹ̀ káàkiri bí òórùn dídùn níbi gbogbo.
15. Nítorí àwa ni òórùn dídùn tí Kristi fi rúbọ sí Ọlọrun lọ́dọ̀ àwọn tí à ń gbàlà ati àwọn tí ń ṣègbé.
16. Fún àwọn tí wọn ń ṣègbé, a dàbí òórùn tí n pani, ṣugbọn fún àwọn tí à ń gbàlà, a dàbí òórùn dídùn tí ó ń fún wọn ní ìyè. Ta ló tó ṣe irú iṣẹ́ yìí?