Joṣua 11:5-14 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Gbogbo àwọn ọba wọnyi parapọ̀, wọ́n kó gbogbo ọmọ ogun wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n sì pàgọ́ sí etí odò Meromu.

6. OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí pé ní ìwòyí ọ̀la, òkú wọn ni n óo fi lé Israẹli lọ́wọ́. Dídá ni kí ẹ dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, kí ẹ sì sun gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”

7. Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá jálù wọ́n lójijì ní etí odò Meromu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn jagun.

8. OLUWA fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n. Wọ́n lé wọn títí dé Sidoni ati Misirefoti Maimu, ati apá ìlà oòrùn títí dé àfonífojì Misipa, wọ́n pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan.

9. Joṣua ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ pé kí ó ṣe sí wọn: ó dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, ó sì sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn níná.

10. Joṣua bá yipada, ó gba ìlú Hasori, ó sì fi idà pa ọba wọn, nítorí pé Hasori ni olú-ìlú ìjọba ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ rí.

11. Wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà láìku ẹyọ ẹnìkan, wọ́n sì sun ìlú Hasori níná.

12. Joṣua gba gbogbo ìlú àwọn ọba náà, ó kó àwọn ọba wọn, ó fi idà pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí Mose iranṣẹ OLUWA ti pàṣẹ fún un.

13. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò sun èyíkéyìí ninu àwọn ìlú tí wọ́n kọ́ sórí òkítì níná, àfi Hasori nìkan ni Joṣua dáná sun.

14. Àwọn ọmọ Israẹli kó gbogbo dúkìá ìlú náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní ìkógun, ṣugbọn wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀ run patapata, wọn kò dá ẹyọ ẹnìkan sí.

Joṣua 11