Johanu 6:51-67 BIBELI MIMỌ (BM)

51. Èmi ni oúnjẹ tí ó wà láàyè tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ninu oúnjẹ yìí, olúwarẹ̀ yóo wà láàyè laelae. Oúnjẹ tí èmi yóo fi fún un ni ẹran ara mi tí yóo fi ìyè fún gbogbo ayé.”

52. Gbolohun yìí dá àríyànjiyàn sílẹ̀ láàrin àwọn Juu. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn pé, “Báwo ni eléyìí ti ṣe lè fún wa ní ẹran-ara rẹ̀ jẹ?”

53. Jesu wá wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ̀yin kò bá jẹ ẹran ara ọmọ eniyan, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò lè ní ìyè ninu yín.

54. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran-ara mi, tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ní ìyè ainipẹkun, èmi yóo sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.

55. Ẹran-ara mi ni oúnjẹ gidi, ẹ̀jẹ̀ mi sì ni ohun mímu iyebíye.

56. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran-ara mi, tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, olúwarẹ̀ ń gbé inú mi, èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀.

57. Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wà láàyè nítorí ti Baba. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran ara mi, yóo yè nítorí tèmi.

58. Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀, kì í ṣe irú èyí tí àwọn baba yín jẹ, tí wọ́n sì kú sibẹsibẹ. Ẹni tí ó bá jẹ oúnjẹ yìí yóo wà láàyè laelae.”

59. Jesu sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn ní Kapanaumu.

60. Ọpọlọpọ tí ó gbọ́ ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé, “Ọ̀rọ̀ yìí le, kò sí ẹni tí ó lè gba irú rẹ̀!”

61. Nígbà tí Jesu rí i pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn nítorí rẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Ṣé ọ̀rọ̀ yìí ni ó mú kí ọkàn yín dààmú?

62. Tí ẹ bá wá rí Ọmọ-Eniyan tí ń gòkè lọ sí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀ ńkọ́?

63. Ẹ̀mí ní ń sọ eniyan di alààyè, ẹran-ara kò ṣe anfaani kankan. Ọ̀rọ̀ tí mo ti ba yín sọ jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀mí ati ti ìyè.

64. Ṣugbọn àwọn tí kò gbàgbọ́ wà ninu yín.” Jesu sọ èyí nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ó ti mọ àwọn tí kò gbàgbọ́ ati ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.

65. Ó ní, “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, àfi bí Baba mi bá ṣí ọ̀nà fún un láti wá.”

66. Nítorí èyí, ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pada lẹ́yìn rẹ̀, wọn kò tún bá a rìn mọ́.

67. Jesu bá bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila pé, “Ẹ̀yin náà fẹ́ lọ bí?”

Johanu 6