34. Àwọn eniyan bi í pé, “A gbọ́ ninu òfin pé Mesaya wà títí lae. Kí ni ìtumọ̀ ohun tí o sọ pé dandan ni kí á gbé Ọmọ-Eniyan sókè? Ta ni ń jẹ́ Ọmọ-Eniyan?”
35. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìmọ́lẹ̀ wà láàrin yín fún àkókò díẹ̀ sí i. Ẹ máa rìn níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má baà bò yín mọ́lẹ̀. Ẹni tí ó bá ń rìn ninu òkùnkùn kò mọ ibi tí ó ń lọ.
36. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ náà gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀.”Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó fara pamọ́ fún wọn.
37. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lójú wọn, sibẹ wọn kò gbà á gbọ́.
38. Èyí mú kí ọ̀rọ̀ wolii Aisaya ṣẹ nígbà tí ó sọ pé,“Oluwa, ta ni ó gba ìròyìn wa gbọ́?Ta ni a fi agbára Oluwa hàn fún?”
39. Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Aisaya tún sọ pé,
40. “Ojú wọn ti fọ́,ọkàn wọn sì ti le;kí wọn má baà fi ojú wọn ríran,kí òye má baà yé wọn.Kí wọn má baà yipada,kí n má baà wò wọ́n sàn.”
41. Aisaya sọ nǹkan wọnyi nítorí ó rí ògo Jesu, ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀.
42. Sibẹ ọpọlọpọ ninu àwọn aṣaaju gbà á gbọ́; ṣugbọn wọn kò jẹ́wọ́ nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Farisi, kí wọn má baà yọ wọ́n kúrò ninu àwùjọ;
43. nítorí wọ́n fẹ́ràn ìyìn eniyan ju ìyìn Ọlọrun lọ.
44. Jesu bá kígbe pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, kì í ṣe èmi ni ó gbàgbọ́ bíkòṣe ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.
45. Ẹni tí ó bá rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi.
46. Mo wá sinu ayé bí ìmọ́lẹ̀, kí ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ má baà wà ninu òkùnkùn.
47. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò bá pa á mọ́, èmi kò ní dá a lẹ́jọ́, nítorí n kò wá sí ayé láti ṣe ìdájọ́, ṣugbọn mo wá láti gba aráyé là.
48. Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, ó ní ohun tí yóo dá a lẹ́jọ́, ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ ni yóo dá a lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn.