Joẹli 1:7-15 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Wọ́n ti run ọgbà àjàrà mi,wọ́n ti já àwọn ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi,wọ́n ti bó gbogbo èèpo ara rẹ̀,wọ́n ti wó o lulẹ̀,àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ti di funfun.

8. Ẹ sọkún bí ọmọge tí ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora,nítorí ikú àfẹ́sọ́nà ìgbà èwe rẹ̀.

9. A ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu dúró ní ilé OLUWA,àwọn alufaa tíí ṣe iranṣẹ OLUWA ń ṣọ̀fọ̀.

10. Ilẹ̀ ti gbẹ, ó ń ṣọ̀fọ̀,nítorí a ti run ọkà, àjàrà ti tán, epo olifi sì ń tán lọ.

11. Ẹ banújẹ́, ẹ̀yin àgbẹ̀,ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ẹ̀yin tí ẹ̀ ń tọ́jú ọgbà àjàrà,nítorí ọkà alikama ati ọkà baali,ati nítorí pé ohun ọ̀gbìn ti ṣègbé.

12. Èso àjàrà ti rọ,igi ọ̀pọ̀tọ́ sì ti ń gbẹ.Igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ ati igi ápù, ati gbogbo àwọn igi eléso ti gbẹ,inú ọmọ eniyan kò sì dùn mọ́.

13. Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ sì sọkún, ẹ̀yin alufaa,ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,ẹ̀yin tí ẹ̀ ǹ ṣiṣẹ́ ní ibi pẹpẹ ìrúbọ.Ẹ̀yin òjíṣẹ́ Ọlọrun mi, ẹ wọlé,kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora sùn,nítorí a ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu dúró ní ilé Ọlọrun yín.

14. Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì pe àpèjọ.Ẹ pe àwọn àgbààgbà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà jọ sí ilé OLUWA Ọlọrun yín,kí ẹ sì kígbe pe OLUWA.

15. Ó ṣe! Ọjọ́ náà ń bọ̀,ọjọ́ OLUWA dé tán!Ọjọ́ náà yóo dé bí ọjọ́ ìparun láti ọ̀dọ̀ Olodumare.

Joẹli 1