Jeremaya 51:12-29 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ẹ gbé àsíá kan sókè, ẹ gbé e ti odi Babiloni;ẹ ṣe ìsénà tí ó lágbára.Ẹ fi àwọn aṣọ́nà sí ipò wọn;ẹ dira fún àwọn kan, kí wọn sápamọ́,nítorí OLUWA ti pinnu, ó sì ti ṣe ohun tí ó sọ nípa àwọn ará Babiloni.

13. Ìwọ Babiloni, tí odò yí ká,tí ìṣúra rẹ pọ̀ lọpọlọpọ,òpin ti dé bá ọ,okùn tí ó so ayé rẹ rọ̀ ti já.

14. OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi ara rẹ̀ búra,pé òun yóo mú kí àwọn eniyan kún inú rẹ bí eṣú,wọn yóo sì kígbe ìṣẹ́gun lé ọ lórí.

15. OLUWA ni ó fi agbára rẹ̀ dá ilé ayé,tí ó fi ìdí ayé múlẹ̀ pẹlu ìmọ̀ rẹ̀,ó sì fi òye rẹ̀ ta àwọn ọ̀run bí aṣọ.

16. Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀,ojú ọ̀run yóo kún fún alagbalúgbú omi,ó sì ń mú ìkùukùu gòkè láti òpin ilẹ̀ ayé.Ó dá mànàmáná fún òjò,ó sì mú ìjì jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀.

17. Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan, wọn kò sì ní ìmọ̀,gbogbo alágbẹ̀dẹ wúrà sì gba ìtìjú lórí oriṣa tí wọn dà;nítorí pé irọ́ ni ère tí wọ́n rọ,wọn kò ní èémí.

18. Asán ni wọ́n, wọ́n ń ṣini lọ́nà,píparun ni wọn yóo parun, ní ọjọ́ ìjìyà wọn.

19. Ọlọrun ti Jakọbu kò dàbí àwọn wọnyi,nítorí pé òun ní ẹlẹ́dàá ohun gbogbo;ẹ̀yà Israẹli ni eniyan tirẹ̀,OLUWA àwọn ọmọ ogun sì ni orúkọ rẹ̀.OLUWA sọ fún Babiloni pé,

20. “Ìwọ ni òòlù ati ohun ìjà mi:ìwọ ni mo fi wó àwọn orílẹ̀-èdè wómúwómú,ìwọ ni mo sì fi pa àwọn ìjọba run.

21. Ìwọ ni mo fi lu ẹṣin ati ẹni tí ń gùn ún pa;ìwọ ni mo fi wó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn tí ń bẹ ninu wọn.

22. Ìwọ ni mo fi lu tọkunrin tobinrin pa,ìwọ ni mo fi lu tọmọde, tàgbà pa,ìwọ ni mo sì fi run àwọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin.

23. Ìwọ ni mo fi pa olùṣọ́-aguntan ati agbo ẹran rẹ̀ rẹ́,ìwọ ni mo fi run àgbẹ̀ ati àwọn alágbàro rẹ̀,ìwọ ni mo fi ṣẹ́ apá àwọn gomina ati ti àwọn olórí ogun.”

24. OLUWA ní,“Níṣojú yín ni n óo fi san ẹ̀san fún Babiloni,ati gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Kalidea,fún gbogbo ibi tí wọ́n ṣe sí Sioni;èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

25. Wò ó! Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè ìparun,tí ò ń pa gbogbo ayé run.N óo gbá ọ mú, n óo tì ọ́ lulẹ̀ láti orí àpáta,n óo sì sọ ọ́ di òkè tí ó jóná.

26. Wọn kò ní rí òkúta kan mú jáde ninu rẹ,tí eniyan lè fi ṣe òkúta igun ilé;tabi tí wọn lè fi ṣe ìpìlẹ̀ ilé,ń ṣe ni o óo wó lulẹ̀ títí ayé.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

27. “Ẹ ta àsíá sórí ilẹ̀ ayé,ẹ fun fèrè ogun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í,ẹ sì pe àwọn ìjọba jọ láti dojú kọ ọ́;àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè bíi Ararati, Minni, ati Aṣikenasi.Ẹ yan balogun tí yóo gbógun tì í;ẹ kó ẹṣin wá, kí wọn pọ̀ bí eṣú.

28. Kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í,kí àwọn ọba ilẹ̀ Media múra, pẹlu àwọn gomina wọn,ati àwọn ẹmẹ̀wà wọn,ati gbogbo ilẹ̀ tí ó wà lábẹ́ wọn.

29. Jìnnìjìnnì bo gbogbo ilẹ̀ náà,wọ́n wà ninu ìrora,nítorí pé OLUWA kò yí ìpinnu rẹ̀ lórí Babiloni pada,láti sọ ilẹ̀ náà di ahoro,láìsí ẹnìkan kan ninu rẹ̀ mọ́.

Jeremaya 51