11. A óo wí fún àwọn eniyan yìí, ati àwọn ará Jerusalẹmu ní ìgbà náà pé afẹ́fẹ́ gbígbóná kan ń fẹ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè, ninu pápá, ó ń fẹ́ bọ̀ sọ́dọ̀ àwọn eniyan mi; kì í ṣe afẹ́fẹ́ lásán tíí fẹ́ pàǹtí ati ìdọ̀tí dànù.
12. Ìjì tí yóo ti ọ̀dọ̀ mi wá yóo le jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nisinsinyii èmi ni mò ń fi ọ̀rọ̀ mi dá wọn lẹ́jọ́.
13. Ẹ wò ó! Ó ń bọ̀ bí ìkùukùu,kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ dàbí ìjì.Àwọn ẹṣin rẹ̀ yára ju àṣá lọ.A gbé, nítorí ìparun dé bá wa.
14. Ìwọ Jerusalẹmu, fọ ibi dànù kúrò lọ́kàn rẹ,kí á lè gbà ọ́ là.Yóo ti pẹ́ tó tí èrò burúkú yóo fi máa wà lọ́kàn rẹ?
15. Nítorí a gbọ́ ohùn kan láti ilẹ̀ Dani,tí ń kéde ibi láti òkè Efuraimu.
16. Ẹ kìlọ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè pé ó ń bọ̀,kéde fún Jerusalẹmu pé,àwọn ológun tí ń dó ti ìlú ń bọ̀, láti ilẹ̀ òkèèrè.Wọ́n ń kọ lálá sí àwọn ìlú Juda.
17. Wọ́n yí i ká bí àwọn tí ó ń ṣọ́ oko,nítorí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA.OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
18. Ìrìn ẹsẹ̀ rẹ ati ìwà rẹni ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi dé bá ọ.Ìjìyà rẹ nìyí, ó sì korò;ó ti dé oókan àyà rẹ.
19. Oró ò! Oró ò!Mò ń jẹ̀rora!Àyà mi ò!Àyà mi ń lù kìkìkì,n kò sì lè dákẹ́;nítorí mo gbọ́ ìró fèrè ogun, ati ariwo ogun.
20. Àjálù ń ṣubú lu àjálù,gbogbo ilẹ̀ ti parun.Lójijì àgọ́ mi wó lulẹ̀,aṣọ títa mi sì fàya ní ìṣẹ́jú kan.
21. Yóo ti pẹ́ tó tí n óo máa wo àsíá ogun,tí n óo sì máa gbọ́ fèrè ogun?
22. OLUWA ní, “Nítorí pé àwọn eniyan mi gọ̀,wọn kò mọ̀ mí.Òmùgọ̀ ọmọ ni wọ́n;wọn kò ní òye.Ọgbọ́n àtiṣe ibi kún inú wọn:ṣugbọn wọn kò mọ rere ṣe.”
23. Mo bojú wo ilé ayé, ilé ayé ṣófo,ó rí júujùu;mo ṣíjú wo ojú ọ̀run,kò sí ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀.
24. Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n ń mì tìtì,gbogbo òkè kéékèèké ń sún lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún.