Jeremaya 23:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní, “Àwọn olùṣọ́-aguntan tí wọn ń tú àwọn agbo aguntan mi ká, tí wọn ń run wọ́n gbé!”

2. Nítorí náà, OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn tí ó fi ṣọ́ àwọn eniyan rẹ̀, láti máa bojútó wọn pé, “Ẹ ti tú àwọn aguntan mi ká, ẹ ti lé wọn dànù, ẹ kò sì tọ́jú wọn. N óo wá ṣe ìdájọ́ fun yín nítorí iṣẹ́ ibi yín, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

3. N óo kó àwọn tí wọ́n kù ninu àwọn aguntan mi jọ láti gbogbo ibi tí mo lé wọn lọ. N óo kó wọn pada sinu agbo wọn. Wọn óo bímọ lémọ, wọn óo sì máa pọ̀ sí i.

4. N óo wá fún wọn ní olùṣọ́ mìíràn tí yóo tọ́jú wọn. Ẹ̀rù kò ní bà wọ́n mọ́, wọn kò ní fòyà, ọ̀kankan ninu wọn kò sì ní sọnù, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

5. “Wò ó! Àkókò kan ń bọ̀, tí n óo gbé Ẹ̀ka olódodo kan dìde ninu ìdílé Dafidi. Yóo jọba, yóo hùwà ọlọ́gbọ́n, yóo sì ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ náà.

6. Juda yóo rí ìgbàlà ní ìgbà tirẹ̀, Israẹli yóo sì wà láìléwu. Orúkọ tí a óo máa pè é ni ‘OLUWA ni òdodo wa.’

7. “Nítorí náà àkókò kan ń bọ̀, tí wọn kò ní máa búra ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti mọ́,

8. ṣugbọn tí wọn yóo máa wí pé, ‘Ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ ilé Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá, ati gbogbo ilẹ̀ tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ, tí ó sì mú wọn pada sí ilẹ̀ wọn.’ Wọn óo wá máa gbé orí ilẹ̀ wọn nígbà náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

9. Ọkàn mi bàjẹ́ nítorí àwọn wolii,gbogbo ara mi ń gbọ̀n.Mo dàbí ọ̀mùtí tí ó ti mu ọtí yó,mo dàbí ẹni tí ọtí ń pa,nítorí OLUWA, ati nítorí ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.

10. Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún àgbèrè ẹ̀sìn,ọ̀nà ibi ni wọ́n ń tọ̀,wọn kò sì lo agbára wọn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́nítorí ègún, ilẹ̀ ti di gbígbẹgbogbo pápá oko ló ti gbẹ.

11. Ati wolii, ati alufaa, ìwà burúkú ni wọ́n ń hù,ní ilé mi pàápàá mo rí iṣẹ́ ibi wọn,èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

12. Nítorí náà ọ̀nà wọn yóo dàbí ọ̀nà tí ń yọ̀ ninu òkùnkùn,a óo tì wọ́n sinu rẹ̀, wọn yóo sì ṣubú,nítorí n óo mú kí ibi bá wọn ní ọdún ìjìyà wọn.

13. Mo rí nǹkankan tí ó burú lọ́wọ́ àwọn wolii Samaria:Ẹ̀mí oriṣa Baali ni wọ́n fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀;wọ́n sì ń ṣi àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, lọ́nà.

14. Mo rí nǹkankan tí ó bani lẹ́rù lọ́wọ́ àwọn wolii Jerusalẹmu:Wọ́n ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn,wọ́n ń hùwà èké;wọ́n ń ran àwọn ẹni ibi lọ́wọ́,kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi rẹ̀.Gbogbo wọn ti di ará Sodomu lójú mi,àwọn ará Jerusalẹmu sì dàbí àwọn ará Gomora.

15. Nítorí náà OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa àwọn wolii pé:N óo fún wọn ní ewé igi kíkorò jẹ,n óo fún wọn ní omi májèlé mu.Nítorí pé láti ọ̀dọ̀ àwọn wolii Jerusalẹmuni ìwà burúkú ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ yìí.

Jeremaya 23