Nítorí náà OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa àwọn wolii pé:N óo fún wọn ní ewé igi kíkorò jẹ,n óo fún wọn ní omi májèlé mu.Nítorí pé láti ọ̀dọ̀ àwọn wolii Jerusalẹmuni ìwà burúkú ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ yìí.