Jẹnẹsisi 37:15-25 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Níbi tí ó ti ń rìn kiri ninu pápá ni ọkunrin kan bá rí i, ó bi í pé, “Kí ni ò ń wá?”

16. Josẹfu dáhùn pé, “Àwọn arakunrin mi ni mò ń wá, jọ̀wọ́, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n da agbo ẹran wọn lọ?”

17. Ọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Wọ́n ti kúrò níhìn-ín, mo gbọ́ tí wọn ń bá ara wọn sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Dotani.’ ” Josẹfu bá tún lépa wọn lọ sí Dotani, ó sì bá wọn níbẹ̀.

18. Bí wọ́n ti rí i tí ó yọ lókèèrè, kí ó tilẹ̀ tó súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn láti pa á.

19. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ara wọn pé, “Ẹ wò ó, alálàá ni ó ń bọ̀ yìí!

20. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí á wọ́ ọ sinu kòtò kan, kí á sọ pé ẹranko burúkú kan ni ó pa á jẹ, kí á wá wò ó bí àlá rẹ̀ yóo ṣe ṣẹ.”

21. Ṣugbọn nígbà tí Reubẹni gbọ́, ó gbà á kalẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó ní, “Ẹ má jẹ́ kí á pa á.

22. Ẹ má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, jíjù ni kí ẹ jù ú sinu kànga gbígbẹ láàrin aginjù yìí, ẹ má pa á lára rárá.” Ó fẹ́ fi ọgbọ́n yọ ọ́ lọ́wọ́ wọn, kí ó lè fi í ranṣẹ sí baba wọn pada.

23. Bí Josẹfu ti dé ọ̀dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀, wọ́n fi ipá bọ́ ẹ̀wù aláràbarà rẹ̀ lọ́rùn rẹ̀,

24. wọ́n gbé e jù sinu kànga kan tí kò ní omi ninu.

25. Bí wọ́n ti jókòó tí wọ́n fẹ́ máa jẹun, ojú tí wọ́n gbé sókè, wọ́n rí ọ̀wọ́ àwọn ará Iṣimaeli kan, wọ́n ń bọ̀ láti Gileadi, wọ́n ń lọ sí Ijipti, àwọn ràkúnmí wọn ru turari, ìkunra olóòórùn dídùn ati òjíá.

Jẹnẹsisi 37