Jẹnẹsisi 25:9-26 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Àwọn ọmọ rẹ̀, Isaaki ati Iṣimaeli, sin òkú rẹ̀ sinu ihò òkúta Makipela, ninu pápá Efuroni, ọmọ Sohari, ará Hiti, níwájú Mamure.

10. Ilẹ̀ tí Abrahamu rà lọ́wọ́ àwọn ará Hiti ni wọ́n sin ín sí pẹlu Sara aya rẹ̀,

11. Lẹ́yìn ikú Abrahamu, Ọlọrun bukun Isaaki ọmọ rẹ̀. Isaaki sì ń gbé Beeri-lahai-roi.

12. Ìran Iṣimaeli, ọmọ Abrahamu, tí Hagari, ará Ijipti, ọmọ-ọ̀dọ̀ Sara bí fún un nìyí:

13. Àwọn ọmọkunrin Iṣimaeli nìwọ̀nyí bí a ti bí wọn tẹ̀lé ara wọn: Nebaiotu, Kedari, Adibeeli,

14. Mibisamu, Miṣima, Duma, Masa,

15. Hadadi, Tema, Jeturi, Nafiṣi ati Kedema.

16. Àwọn ni ọmọkunrin Iṣimaeli. Wọ́n jẹ́ ọba ẹ̀yà mejila, orúkọ wọn ni wọ́n sì fi ń pe àwọn ìletò ati àgọ́ wọn.

17. Iye ọdún tí Iṣimaeli gbé láyé jẹ́ ọdún mẹtadinlogoje (137). Nígbà tí ó kú a sin ín pẹlu àwọn eniyan rẹ̀.

18. Àwọn ọmọ Iṣimaeli sì ń gbé ilẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Hafila títí dé Ṣuri, tí ó wà ní òdìkejì Ijipti, ní apá Asiria. Wọ́n tẹ̀dó sí òdìkejì àwọn eniyan wọn.

19. Ìran Isaaki ọmọ Abrahamu nìyí, Abrahamu ni baba Isaaki.

20. Nígbà tí Isaaki di ẹni ogoji ọdún, ó fẹ́ Rebeka. Rebeka jẹ́ ọmọ Betueli, ará Aramea, tí ń gbé Padani-aramu, ó sì tún jẹ́ arabinrin Labani, ara Aramea.

21. Isaaki gbadura sí OLUWA fún aya rẹ̀ tí ó yàgàn, OLUWA gbọ́ adura rẹ̀, Rebeka aya rẹ̀ sì lóyún.

22. Àwọn ọmọ ń ti ara wọn síhìn-ín sọ́hùn-ún ninu rẹ̀, ó sì wí pé, “Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni yóo máa rí, kí ni mo kúkú wà láàyè fún?” Ó bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà wò lọ́dọ̀ OLUWA.

23. OLUWA wí fún un pé,“Orílẹ̀-èdè meji ni ó wà ninu rẹ,a óo sì pín àwọn oríṣìí eniyan meji tí o óo bí níyà,ọ̀kan yóo lágbára ju ekeji lọ,èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo sì máa sin àbúrò.”

24. Nígbà tí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ pé, ìbejì ni ó bí nítòótọ́.

25. Èyí àkọ́bí pupa, gbogbo ara rẹ̀ dàbí aṣọ onírun. Nítorí náà ni wọ́n fi sọ ọ́ ní Esau.

26. Nígbà tí wọ́n bí èyí ekeji, rírọ̀ ni ó fi ọwọ́ kan rọ̀ mọ́ èyí àkọ́bí ní gìgísẹ̀. Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní Jakọbu. Ẹni ọgọta ọdún ni Isaaki nígbà tí Rebeka bí wọn.

Jẹnẹsisi 25