Isikiẹli 27:13-22 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Àwọn ará Jafani, Tubali, ati Meṣeki ń bá ọ ṣòwò; wọ́n ń kó ẹrú ati ohun èlò idẹ wá fún ọ, wọn fi ń gba àwọn nǹkan tí ò ń tà.

14. Àwọn ará Beti Togama a máa kó ẹṣin, ati ẹṣin ogun, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí ò ń tà.

15. Àwọn ará Didani ń bá ọ ṣòwò, ọpọlọpọ etíkun ni ẹ tí ń tajà, wọ́n ń fi eyín erin ati igi Ẹboni ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọ.

16. Àwọn ará Edomu bá ọ ṣòwò nítorí ọpọlọpọ ọjà tí ò ń tà. Òkúta emeradi, aṣọ àlàárì, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́ tẹ́ẹ́rẹ́, iyùn ati òkúta agate ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọ.

17. Juda ati ilé Israẹli bá ọ ṣòwò: wọ́n ń kó ọkà, èso olifi, àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́, oyin, òróró ati òrí wá láti fi ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí ò ń tà.

18. Àwọn ará Damasku bá ọ ṣòwò nítorí ọpọlọpọ ọjà ati àwọn nǹkan olówó iyebíye tí ò ń tà, wọ́n mú ọtí waini ati irun aguntan funfun wá láti Heliboni.

19. Àwọn ará Fedani ati Jafani láti Usali a máa wá fi ọtí waini pààrọ̀ ohun tí ò ń tà; wọn a kó àwọn nǹkan èlò irin wá, ati igi kasia.

20. Àwọn ará Dedani náà ń bá ọ ṣòwò, wọ́n ń kó aṣọ gàárì tí wọ́n fi ń gun ẹṣin wá.

21. Àwọn ará Arabia ati àwọn olóyè Kedari ni àwọn oníbàárà rẹ pataki, wọn a máa ra ọ̀dọ́ aguntan, àgbò, ati ewúrẹ́ lọ́wọ́ rẹ.

22. Àwọn oníṣòwò Ṣeba ati ti Raama náà a máa bá ọ ra ọjà, oríṣìíríṣìí turari olóòórùn dídùn ati òkúta olówó iyebíye ati wúrà ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́wọ́ rẹ.

Isikiẹli 27