5. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n súnmọ́ ọ ati àwọn tí wọ́n jìnnà sí ọ yóo máa fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́, ìwọ tí o kò níyì, tí o kún fún ìdàrúdàpọ̀.
6. Wo àwọn olórí ní ilẹ̀ Israẹli tí wọ́n wà ninu rẹ, olukuluku ti pinnu láti máa lo agbára rẹ̀ láti máa paniyan.
7. Àwọn ọmọ kò náání baba ati ìyá wọn ninu rẹ; wọ́n sì ń ni àwọn àjèjì ninu rẹ lára; wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn aláìníbaba ati opó.
8. O kò bìkítà fún àwọn ohun mímọ́ mi, o sì ti ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́.
9. Àwọn eniyan inú rẹ ń parọ́ láti paniyan. Wọ́n ń jẹbọ kiri lórí àwọn òkè ńláńlá, wọ́n sì ń ṣe ohun ìtìjú.
10. Àwọn mìíràn ń bá aya baba wọn lòpọ̀, wọ́n sì ń fi ipá bá obinrin lòpọ̀ ní ìgbà tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́.