5. Àwọn tí a wí yìí ṣiwaju wa lọ, wọ́n lọ dúró dè wá ní Tiroasi.
6. Àwa náà wá wọkọ̀ ojú omi ní Filipi lẹ́yìn Àjọ̀dún Àìwúkàrà, a bá wọn ní Tiroasi lọ́jọ́ karun-un. Ọjọ́ meje ni a lò níbẹ̀.
7. Ní alẹ́ ọjọ́ Satide, a péjọ láti jẹun; Paulu wá ń bá àwọn onigbagbọ sọ̀rọ̀. Ó ti wà lọ́kàn rẹ̀ pé lọ́jọ́ keji ni òun óo tún gbéra. Nítorí náà ó sọ̀rọ̀ títí dòru.
8. Àtùpà pọ̀ ninu iyàrá òkè níbi tí a péjọ sí.
9. Ọdọmọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Yutiku jókòó lórí fèrèsé. Ó ti sùn lọ níbi tí Paulu gbé ń sọ̀rọ̀ lọ títí. Nígbà tí oorun wọ̀ ọ́ lára, ó ré bọ́ sílẹ̀ láti orí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kẹta. Nígbà tí wọn óo gbé e, ó ti kú.
10. Paulu bá sọ̀kalẹ̀, ó gbá a mú, ó dùbúlẹ̀ lé e lórí. Ó ní, “Ẹ má dààmú, nítorí ẹ̀mí rẹ̀ ṣì wà ninu rẹ̀.”
11. Nígbà tí ó pada sókè, ó gé burẹdi, ó jẹun. Ó wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. Ó bá jáde lọ.
12. Wọ́n mú ọmọ náà lọ sílé láàyè. Èyí sì tù wọ́n ninu lọpọlọpọ.
13. A bọ́ siwaju, a wọkọ̀ ojú omi lọ sí Asọsi. Níbẹ̀ ni a lérò pé Paulu yóo ti wá bá wa tí òun náà yóo sì wọkọ̀. Òun ló ṣe ètò bẹ́ẹ̀ nítorí ó fẹ́ fẹsẹ̀ rìn dé ibẹ̀.
14. Nígbà tí ó bá wa ní Asọsi, ó wọnú ọkọ̀ wa, a bá lọ sí Mitilene.
15. Ní ọjọ́ keji a kúrò níbẹ̀, a dé òdìkejì erékùṣù Kiosi. Ní ọjọ́ kẹta a dé Samosi. Ní ọjọ́ kẹrin a dé Miletu.
16. Nítorí Paulu ti pinnu láti wọkọ̀ kọjá Efesu, kí ó má baà pẹ́ pupọ ní Esia, nítorí ó ń dàníyàn pé bí ó bá ṣeéṣe, òun fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Pẹntikọsti ní Jerusalẹmu.