1. Ní ọjọ́ Pẹntikọsti, gbogbo wọn wà pọ̀ ní ibìkan náà.
2. Lójijì ìró kan dún láti ọ̀run, ó dàbí ìgbà tí afẹ́fẹ́ líle bá ń fẹ́, ó sì kún gbogbo inú ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó.
3. Wọ́n rí nǹkankan tí ó dàbí ahọ́n iná, tí ó pín ara rẹ̀, tí ó sì bà lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn.
4. Gbogbo wọn bá kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ oríṣìíríṣìí èdè mìíràn gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn láti máa sọ.
5. Ní àkókò náà, àwọn Juu tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn ti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé wá, wọ́n wà ní Jerusalẹmu.
6. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró yìí, àwọn eniyan rọ́ wá. Ẹnu yà wọ́n nítorí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọ́ tí wọn ń sọ èdè tirẹ̀.
7. Èyí dà wọ́n láàmú, ó sì yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ní, “Ṣebí ará Galili ni gbogbo àwọn tí ó ń sọ̀rọ̀ wọnyi?
8. Kí ló dé tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa fi gbọ́ tí wọn ń sọ èdè abínibí rẹ̀?