10. Gbàrà tí ó rí ìran náà, a wá ọ̀nà láti lọ sí Masedonia; a pinnu pé Ọlọrun ni ó pè wá láti lọ waasu fún wọn níbẹ̀.
11. Nígbà tí a wọ ọkọ̀ láti Tiroasi, a lọ tààrà sí Samotirake. Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Neapoli.
12. Láti ibẹ̀, a lọ sí Filipi tíí ṣe olú-ìlú ilẹ̀ Masedonia. Àwọn ará Romu ni wọ́n tẹ ìlú yìí dó. A bá wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan.
13. Ní Ọjọ́ Ìsinmi a jáde lọ sẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá odò, níbi tí a rò pé a óo ti rí ibi tí wọn máa ń gbadura. A bá jókòó, a bá àwọn obinrin tí ó péjọ níbẹ̀ sọ̀rọ̀.
14. Obinrin kan wà níbẹ̀ tí ó ń jẹ́ Lidia, ará Tiatira, tí ó ń ta aṣọ àlàárì. Ó jẹ́ ẹnìkan tí ó ń sin Ọlọrun. Ó fetí sílẹ̀, Ọlọrun ṣí i lọ́kàn láti gba ohun tí Paulu ń sọ.
15. Òun ati àwọn ará ilé rẹ̀ gba ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀ wá pé, bí a bá gbà pé òun jẹ́ onigbagbọ nítòótọ́, kí á máa bọ̀ ní ilé òun kí á máa bá àwọn gbé. Ó tẹnu mọ́ ọn títí a fi gbà.
16. Ní ọjọ́ kan, bí a ti ń lọ sí ibi adura, a pàdé ọdọmọbinrin kan tí ó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ. Ó ti ń mú èrè pupọ wá fún àwọn olówó rẹ̀ nípa àfọ̀ṣẹ rẹ̀.
17. Ó ń tẹ̀lé Paulu ati àwa náà, ó ń kígbe pé, “Àwọn ọkunrin yìí ni iranṣẹ Ọlọrun Ọ̀gá Ògo; àwọn ni wọ́n ń waasu ọ̀nà ìgbàlà fun yín.”
18. Ó ń ṣe báyìí fún ọjọ́ pupọ. Nígbà tí ara Paulu kò gbà á mọ́, ó yipada, ó sọ fún ẹ̀mí náà pé, “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jesu, jáde kúrò ninu rẹ̀.” Ni ó bá jáde lẹ́sẹ̀ kan náà.
19. Nígbà tí àwọn olówó ọdọmọbinrin náà rí i pé ọ̀nà oúnjẹ wọ́n ti dí, wọ́n ki Paulu ati Sila mọ́lẹ̀, wọ́n fà wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ní ọjà.