Àwọn Ọba Kinni 3:16-27 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ní ọjọ́ kan, àwọn aṣẹ́wó meji kan kó ara wọn wá siwaju Solomoni ọba.

17. Ọ̀kan ninu wọn ní, “Kabiyesi inú ilé kan náà ni èmi ati obinrin yìí ń gbé, ibẹ̀ ló sì wà nígbà tí mo fi bí ọmọkunrin kan.

18. Ọjọ́ kẹta tí mo bí ọmọ tèmi ni obinrin yìí náà bí ọmọkunrin kan. Àwa meji péré ni a wà ninu ilé, kò sí ẹnìkẹta pẹlu wa.

19. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, ó sùn lé ọmọ tirẹ̀ mọ́lẹ̀, ọmọ tirẹ̀ bá kú.

20. Ó bá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, ó wá jí ọmọ tèmi gbé ní ẹ̀gbẹ́ mi nígbà tí mo sùn lọ, ó tẹ́ ẹ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, ó sì tẹ́ òkú ọmọ tirẹ̀ sọ́dọ̀ mi.

21. Nígbà tí mo jí ní ọjọ́ keji láti fún ọmọ ní oúnjẹ, mo rí i pé ó ti kú. Ṣugbọn nígbà tí mo yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní, mo rí i pé kì í ṣe ọmọ tèmi ni.”

22. Ṣugbọn obinrin keji dáhùn pé, “Rárá! Èmi ni mo ni ààyè ọmọ, òkú ọmọ ni tìrẹ.”Ekinni náà tún dáhùn pé, “Irọ́ ni! Ìwọ ló ni òkú ọmọ, ààyè ọmọ ni tèmi.”Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí jiyàn níwájú ọba.

23. Nígbà náà ni Solomoni ọba dáhùn, ó ní, “Ekinni keji yín ń wí pé, òun kọ́ ni òun ni òkú ọmọ, ààyè ni tòun.”

24. Ọba bá ranṣẹ pé kí wọ́n mú idà kan wá. Nígbà tí wọ́n mú un dé,

25. ó pàṣẹ pé kí wọ́n la ààyè ọmọ sí meji, kí wọ́n sì fún àwọn obinrin mejeeji ní ìdajì, ìdajì.

26. Ọkàn ìyá tí ó ni ààyè ọmọ kò gbà á, nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí ọmọ rẹ̀, ó wí fún ọba pé, “Kabiyesi, gbé ààyè ọmọ yìí fún ekeji mi, má pa á rárá.”Ṣugbọn èyí ekeji dáhùn pé, “Rárá! Kò ní jẹ́ tèmi, kò sì ní jẹ́ tìrẹ. Jẹ́ kí wọ́n là á sí meji.”

27. Ọba dáhùn, ó ní, “Ẹ má pa ààyè ọmọ yìí rárá, ẹ gbé e fún obinrin àkọ́kọ́. Òun gan-an ni ìyá rẹ̀.”

Àwọn Ọba Kinni 3