Àwọn Ọba Kinni 12:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Rehoboamu lọ sí Ṣekemu, nítorí pé gbogbo Israẹli ti péjọ níbẹ̀ láti fi jọba.

2. Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati gbọ́ ìròyìn yìí ní Ijipti, (níbẹ̀ ni ó ń gbé láti ìgbà tí ó ti sá lọ fún Solomoni ọba), ó pada wá sílé láti Ijipti.

3. Àwọn ọmọ Israẹli ranṣẹ pè é, òun ati gbogbo wọ́n sì tọ Rehoboamu lọ, wọ́n wí fún un pé,

4. “Àjàgà wúwo ni Solomoni baba rẹ gbé bọ̀ wá lọ́rùn. Ṣugbọn bí o bá dín iṣẹ́ líle baba rẹ yìí kù, tí o sì mú kí ìgbé ayé rọ̀ wá lọ́rùn, a óo máa sìn ọ́.”

Àwọn Ọba Kinni 12