5. Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa Sedekaya, wọ́n bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì túká kúrò lẹ́yìn rẹ̀.
6. Ọwọ́ wọn tẹ Sedekaya, wọ́n bá mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ó sì dá ẹjọ́ fún un.
7. Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni Nebukadinesari ọba yọ ojú Sedekaya, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì mú un lọ sí Babiloni.
8. Ní ọjọ́ keje oṣù karun-un ọdún kọkandinlogun ìjọba Nebukadinesari, ọba Babiloni, Nebusaradani, tí ń ṣiṣẹ́ fún ọba Babiloni, tí ó sì tún jẹ́ olórí àwọn tí ń ṣọ́ Babiloni wá sí Jerusalẹmu.
9. Ó sun ilé OLUWA níná, ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn ilé ńláńlá tí ó wà níbẹ̀ ni ó sì dáná sun.