Àwọn Ọba Keji 16:7-9 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ahasi ranṣẹ lọ bá Tigilati Pileseri, ọba Asiria, ó ní, “Iranṣẹ ati ọmọ rẹ ni mo jẹ́, nítorí náà, jọ̀wọ́ wá gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọba Siria ati ti Israẹli tí wọ́n gbógun tì mí.”

8. Ahasi kó fadaka ati wúrà tí ó wà ninu ilé OLUWA, ati tinú àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin jọ, ó kó o ranṣẹ sí ọba Asiria.

9. Ọba Asiria gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì gbógun ti Damasku, ó ṣẹgun rẹ̀, ó pa Resini ọba, ó sì kó gbogbo àwọn eniyan ìlú náà lẹ́rú lọ sí Kiri.

Àwọn Ọba Keji 16