3. Jẹfuta bá sá jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀, ó ń gbé ilẹ̀ Tobu. Àwọn aláìníláárí ati àwọn oníjàgídíjàgan kan bá kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bá ń bá a digun jalè káàkiri.
4. Nígbà tí ó yá, àwọn ará Amoni gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.
5. Nígbà tí ogun yìí bẹ̀rẹ̀, àwọn àgbààgbà Gileadi lọ mú Jẹfuta wá láti ilẹ̀ Tobu.
6. Wọ́n bẹ Jẹfuta, wọ́n ní, “A fẹ́ lọ gbógun ti àwọn ará Amoni, ìwọ ni a sì fẹ́ kí o jẹ́ balogun wa.”
7. Ṣugbọn Jẹfuta dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí ẹ̀yin ni ẹ kórìíra mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ fi lé mi jáde kúrò ní ilé baba mi? Kí ló dé tí ẹ fi wá sọ́dọ̀ mi nígbà tí ìyọnu dé ba yín?”
8. Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “Ìyọnu tí ó dé bá wa náà ni ó mú kí á wá sọ́dọ̀ rẹ; kí o lè bá wa lọ, láti lọ gbógun ti àwọn ará Amoni. Ìwọ ni a fẹ́ kí o jẹ balogun gbogbo àwa ará Gileadi patapata.”
9. Ó bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ bá mú mi pada wálé, láti bá àwọn ará Amoni jagun, bí OLUWA bá sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ tí mo ṣẹgun wọn, ṣé ẹ gbà pé kí n máa ṣe olórí yín?”
10. Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “OLUWA ni ẹlẹ́rìí láàrin àwa pẹlu rẹ pé, ohun tí o bá wí ni a óo ṣe.”