Iṣe Apo 9:8-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Saulu si dide ni ilẹ; nigbati oju rẹ̀ si là kò ri ohunkan: ṣugbọn nwọn fà a li ọwọ́, nwọn si mu u wá si Damasku.

9. O si gbé ijọ mẹta li airiran, kò si jẹ, bẹ̃ni kò si mu.

10. Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Damasku, ti a npè ni Anania; Oluwa si wi fun u li ojuran pe, Anania. O si wipe, Wò o, emi niyi, Oluwa.

11. Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si lọ si ita ti a npè ni Ọgãnran, ki o si bère ẹniti a npè ni Saulu, ara Tarsu, ni ile Juda: sá wo o, o ngbadura.

12. On si ti ri ọkunrin kan li ojuran ti a npè ni Anania o wọle, o si fi ọwọ́ le e, ki o le riran.

13. Anania si dahùn wipe, Oluwa, mo ti gburó ọkunrin yi lọdọ ọ̀pọ enia, gbogbo buburu ti o ṣe si awọn enia mimọ́ rẹ ni Jerusalemu.

14. O si gbà aṣẹ lati ọdọ awọn olori alufa wá si ihinyi, lati dè gbogbo awọn ti npè orukọ rẹ.

15. Ṣugbọn Oluwa wi fun u pe, Mã lọ: nitori ohun elo àyo li on jẹ fun mi, lati gbe orukọ mi lọ si iwaju awọn Keferi, ati awọn ọba, ati awọn ọmọ Israeli:

16. Nitori emi o fi gbogbo ìya ti kò le ṣaijẹ nitori orukọ mi han a.

17. Anania si lọ, o si wọ̀ ile na; nigbati o si fi ọwọ́ rẹ̀ le e, o ni, Saulu Arakunrin, Oluwa li o rán mi, Jesu ti o fi ara hàn ọ li ọ̀na ti iwọ ba wá, ki iwọ ki o le riran, ki o si kún fun Ẹmí Mimọ́.

18. Lojukanna nkan si bọ kuro li oju rẹ̀ bi ipẹpẹ́: o si riran; o si dide, a si baptisi rẹ̀.

19. Nigbati o si jẹun, ara rẹ̀ mokun: Saulu si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin ni Damasku ni ijọ melokan.

20. Lojukanna o si nwasu Kristi ninu awọn sinagogu pe, Ọmọ Ọlọrun li on iṣe.

21. Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o ngbọ́, nwọn si wipe, Ẹniti o ti fõro awọn ti npè orukọ yi ni Jerusalemu kọ li eyi, ti o si ti itori na wá si ihinyi, lati mu wọn ni didè lọ sọdọ awọn olori alufa?

Iṣe Apo 9