Iṣe Apo 8:5-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Filippi si sọkalẹ lọ si ilu Samaria, o nwasu Kristi fun wọn.

6. Awọn ijọ enia si fi ọkàn kan fiyesi ohun ti Filippi nsọ, nigbati nwọn ngbọ́, ti nwọn si ri iṣẹ ami ti o nṣe.

7. Nitori ọpọ ninu awọn ti o ni ẹmi àimọ́ ti nkigbe lohùn rara, jade wá, ati ọpọ awọn ti ẹ̀gba mbajà, ati awọn amọ́kún, a si ṣe dida ara wọn.

8. Ayọ̀ pipọ si wà ni ilu na.

9. Ṣugbọn ọkunrin kan wà, ti a npè ni Simoni, ti iti ima ṣe oṣó ni ilu na, ti isi mã jẹ ki ẹnu ya awọn ara Samaria, a mã wipe enia nla kan li on:

10. Ẹniti gbogbo wọn bọla fun, ati ewe ati àgba, nwipe, ọkunrin yi ni agbara Ọlọrun ti a npè ni Nla.

11. On ni nwọn si bọlá fun, nitori ọjọ pipẹ li o ti nṣe oṣó si wọn.

12. Ṣugbọn nigbati nwọn gbà Filippi gbọ́ ẹniti nwasu ihinrere ti ijọba Ọlọrun, ati orukọ Jesu Kristi, a baptisi wọn, ati ọkunrin ati obinrin.

13. Simoni tikararẹ̀ si gbagbọ́ pẹlu: nigbati a si baptisi rẹ̀, o si mba Filippi joko, o nwò iṣẹ àmi ati iṣẹ agbara ti nti ọwọ́ Filippi ṣe, ẹnu si yà a.

14. Nigbati awọn aposteli ti o wà ni Jerusalemu si gbọ́ pe awọn ara Samaria ti gbà ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn rán Peteru on Johanu si wọn:

15. Awọn ẹniti o si gbadura fun wọn, nigbati nwọn sọkalẹ, ki nwọn ki o le ri Ẹmí Mimọ́ gbà:

16. Nitori titi o fi di igbana kò ti ibà le ẹnikẹni ninu wọn; kìki a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa ni.

17. Nigbana ni nwọn gbe ọwọ́ le wọn, nwọn si gbà Ẹmí Mimọ́.

18. Nigbati Simoni ri pe nipa gbigbe ọwọ́ leni li a nti ọwọ́ awọn aposteli fi Ẹmí Mimọ́ funni, o fi owo lọ̀ wọn.

19. O wipe, Ẹ fun emi na ni agbara yi pẹlu, ki ẹnikẹni ti mo ba gbe ọwọ́ le, ki o le gbà Ẹmí Mimọ́.

20. Ṣugbọn Peteru da a lohùn wipe, Ki owo rẹ ṣegbé pẹlu rẹ, nitoriti iwọ rò lati fi owo rà ẹ̀bun Ọlọrun.

21. Iwọ kò ni ipa tabi ipín ninu ọ̀ràn yi: nitori ọkàn rẹ kò ṣe dédé niwaju Ọlọrun.

22. Nitorina ronupiwada ìwa buburu rẹ yi, ki o si gbadura sọdọ Ọlọrun, boya yio dari ete ọkàn rẹ jì ọ.

Iṣe Apo 8