2. Awọn enia olufọkànsin si dì okú Stefanu, nwọn si pohùnrére ẹkún kikan sori rẹ̀.
3. Ṣugbọn Saulu, o ndà ijọ enia Ọlọrun ru, o nwọ̀ ojõjũle, o si nmu awọn ọkunrin ati obinrin, o si nfi wọn sinu tubu.
4. Awọn ti nwọn si túka lọ si ibi gbogbo, nwọn nwasu ọ̀rọ na.
5. Filippi si sọkalẹ lọ si ilu Samaria, o nwasu Kristi fun wọn.
6. Awọn ijọ enia si fi ọkàn kan fiyesi ohun ti Filippi nsọ, nigbati nwọn ngbọ́, ti nwọn si ri iṣẹ ami ti o nṣe.
7. Nitori ọpọ ninu awọn ti o ni ẹmi àimọ́ ti nkigbe lohùn rara, jade wá, ati ọpọ awọn ti ẹ̀gba mbajà, ati awọn amọ́kún, a si ṣe dida ara wọn.
8. Ayọ̀ pipọ si wà ni ilu na.
9. Ṣugbọn ọkunrin kan wà, ti a npè ni Simoni, ti iti ima ṣe oṣó ni ilu na, ti isi mã jẹ ki ẹnu ya awọn ara Samaria, a mã wipe enia nla kan li on:
10. Ẹniti gbogbo wọn bọla fun, ati ewe ati àgba, nwipe, ọkunrin yi ni agbara Ọlọrun ti a npè ni Nla.
11. On ni nwọn si bọlá fun, nitori ọjọ pipẹ li o ti nṣe oṣó si wọn.
12. Ṣugbọn nigbati nwọn gbà Filippi gbọ́ ẹniti nwasu ihinrere ti ijọba Ọlọrun, ati orukọ Jesu Kristi, a baptisi wọn, ati ọkunrin ati obinrin.
13. Simoni tikararẹ̀ si gbagbọ́ pẹlu: nigbati a si baptisi rẹ̀, o si mba Filippi joko, o nwò iṣẹ àmi ati iṣẹ agbara ti nti ọwọ́ Filippi ṣe, ẹnu si yà a.
14. Nigbati awọn aposteli ti o wà ni Jerusalemu si gbọ́ pe awọn ara Samaria ti gbà ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn rán Peteru on Johanu si wọn:
15. Awọn ẹniti o si gbadura fun wọn, nigbati nwọn sọkalẹ, ki nwọn ki o le ri Ẹmí Mimọ́ gbà:
16. Nitori titi o fi di igbana kò ti ibà le ẹnikẹni ninu wọn; kìki a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa ni.
17. Nigbana ni nwọn gbe ọwọ́ le wọn, nwọn si gbà Ẹmí Mimọ́.
18. Nigbati Simoni ri pe nipa gbigbe ọwọ́ leni li a nti ọwọ́ awọn aposteli fi Ẹmí Mimọ́ funni, o fi owo lọ̀ wọn.
19. O wipe, Ẹ fun emi na ni agbara yi pẹlu, ki ẹnikẹni ti mo ba gbe ọwọ́ le, ki o le gbà Ẹmí Mimọ́.