Iṣe Apo 7:35-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

35. Mose na yi ti nwọn kọ̀, wipe, Tali o fi ọ jẹ olori ati onidajọ? on na li Ọlọrun rán lọ lati ọwọ́ angẹli, ti o farahàn a ni igbẹ́, lati ṣe olori ati oludande.

36. On li o mu wọn jade, lẹhin igbati o ṣe iṣẹ iyanu ati iṣẹ àmi ni ilẹ Egipti, ati li Okun pupa, ati li aginjù li ogoji ọdún.

37. Eyi ni Mose na ti o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Woli kan li Oluwa Ọlọrun nyin yio gbé dide fun nyin ninu awọn arakunrin nyin, bi emi; on ni ki ẹ gbọ́ tirẹ.

38. Eyi na li ẹniti o wà ninu ijọ ni ijù pẹlu angẹli na ti o ba a sọ̀rọ li òke Sinai, ati pẹlu awọn baba wa: ẹniti o gbà ọ̀rọ ìye lati fifun wa:

39. Ẹniti awọn baba wa kò fẹ gbọ́ tirẹ, ṣugbọn nwọn tì i kuro lọdọ wọn, nwọn si yipada li ọkàn wọn si Egipti;

40. Nwọn wi fun Aaroni pe, Dà oriṣa fun wa ti yio ma tọ̀na ṣaju wa: nitori bi o ṣe ti Mose yi ti o mu wa ti ilẹ Egipti jade wá, a kò mọ̀ ohun ti o ṣe e.

41. Nwọn si yá ere ẹgbọ̀rọ malu ni ijọ wọnni, nwọn si rubọ si ere na, nwọn si nyọ̀ ninu iṣẹ ọwọ́ ara wọn.

42. Ọlọrun si pada, o fi wọn silẹ lati mã sìn ogun ọrun; bi a ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, Ẹnyin ara ile Israeli, ẹnyin ha mu ẹran ti a pa ati ẹbọ fun mi wá bi li ogoji ọdun ni iju?

43. Ẹnyin si tẹwọgbà agọ́ Moloku, ati irawọ oriṣa Remfani, aworan ti ẹnyin ṣe lati mã bọ wọn: emi ó si kó nyin lọ rekọja Babiloni.

Iṣe Apo 7