12. Nigbati awa gúnlẹ ni Sirakuse, awa gbé ibẹ̀ ni ijọ mẹta.
13. Lati ibẹ̀ nigbati awa lọ yiká, awa de Regioni: ati lẹhin ijọ kan afẹfẹ gusù dide, ni ijọ keji rẹ̀ awa si de Puteoli,
14. Nibiti a gbé ri awọn arakunrin, ti nwọn si bẹ̀ wa lati ba wọn gbé ni ijọ meje: bẹ̃li awa si lọ si ìha Romu.
15. Ati lati ibẹ nigbati awọn arakunrin gburó wa, nwọn wá titi nwọn fi de Apii Foroni, ati Arojẹ mẹta, lati pade wa: nigbati Paulu si ri wọn, o dupẹ lọwọ Ọlọrun, o mu ọkàn le.
16. Nigbati awa si de Romu, balogun ọrún fi awọn ondè le olori ẹṣọ́ lọwọ: ṣugbọn nwọn jẹ ki Paulu ki o mã dagbe fun ara rẹ̀ pẹlu ọmọ-ogun ti ṣọ́ ọ.
17. O si ṣe, lẹhin ijọ mẹta, Paulu pè awọn olori Ju jọ: nigbati nwọn si pejọ, o wi fun wọn pe, Ará, biotiṣe pe emi kò ṣe ohun kan lòdi si awọn enia, tabi si iṣe awọn baba wa, sibẹ nwọn fi mi le awọn ara Romu lọwọ li ondè lati Jerusalemu wá.
18. Nigbati nwọn si wádi ọ̀ran mi, nwọn fẹ jọwọ mi lọwọ lọ, nitoriti kò si ọ̀ran ikú lara mi.
19. Ṣugbọn nigbati awọn Ju sọ̀rọ lòdi si i, eyi sún mi lati fi ọ̀ran mi lọ Kesari; kì iṣe pe mo ni nkan lati fi orilẹ-ède mi sùn si.
20. Njẹ nitori ọ̀ran yi ni mo ṣe ranṣẹ pè nyin, lati ri nyin, ati lati ba nyin sọ̀rọ: nitoripe nitori ireti Israeli li a ṣe fi ẹ̀wọn yi dè mi.
21. Nwọn si wi fun u pe, Awa kò ri iwe gbà lati Judea wá nitori rẹ, bẹ̃li ẹnikan ninu awọn arakunrin ti o ti ibẹ̀ wá kò rohin, tabi ki o sọ̀rọ ibi kan si ọ.
22. Ṣugbọn awa nfẹ gbọ́ li ẹnu rẹ ohun ti iwọ rò: nitori bi o ṣe ti ìsin iyapa yi ni, awa mọ̀ pe, nibigbogbo li a nsọ̀rọ lòdi si i.
23. Nigbati nwọn dá ọjọ fun u, ọ̀pọlọpọ wọn li o tọ̀ ọ wá ni ile àgbawọ rẹ̀; awọn ẹniti o sọ asọye ọrọ ijọba Ọlọrun fun, o nyi wọn lọkàn pada sipa ti Jesu, lati inu ofin Mose ati awọn woli wá, lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ.
24. Ẹlomiran si gbà ohun ti o nwi gbọ́, ẹlomiran kò si gbagbọ́.
25. Nigbati ohùn wọn kò ṣọ̀kan lãrin ara wọn, nwọn tuká, lẹhin igbati Paulu sọ̀rọ kan pe, Otitọ li Ẹmí Mimọ́ sọ lati ẹnu woli Isaiah wá fun awọn baba wa,
26. Wipe, Tọ̀ awọn enia wọnyi lọ, ki o si wipe, Ni gbigbọ́ ẹnyin ó gbọ́, kì yio si yé nyin; ati ni riri ẹnyin ó ri, ẹnyin kì yio si woye:
27. Nitoriti àiya awọn enia yi sebọ, etí wọn si wuwo lati fi gbọ́, oju wọn ni nwọn si ti dì: nitori ki nwọn ki o má ba fi oju wọn ri, ki nwọn ki o má ba fi etí wọn gbọ́, ati ki nwọn ki o má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ati ki emi ki o má ba mu wọn larada.
28. Njẹ ki ẹnyin ki o mọ̀ eyi pe, a rán igbala Ọlọrun si awọn Keferi, nwọn ó si gbọ́.