1. NIGBATI gbogbo wa si yọ tan ni awa mọ̀ pe, Melita li a npè erekuṣu na.
2. Kì si iṣe ore diẹ li awọn alaigbede na ṣe fun wa: nitoriti nwọn daná, nwọn si gbà gbogbo wa si ọdọ nitori òjo igba na, ati itori otutù.
3. Nigbati Paulu si ṣà ìdi iwọ́nwọ́n igi jọ, ti o si kó o sinu iná, pamọlẹ kan ti inu oru jade, o dì mọ́ ọ li ọwọ́.
4. Bi awọn alaigbede na si ti ri ẹranko oloró na ti dì mọ́ ọ li ọwọ́, nwọn ba ara wọn sọ pe, Dajudaju apania li ọkunrin yi, ẹniti o yọ ninu okun tan, ṣugbọn ti ẹsan kò si jẹ ki o wà lãye.
5. On si gbọ̀n ẹranko na sinu iná, ohunkohun kan kò ṣe e.
6. Ṣugbọn nwọn nwoye igbati yio wú, tabi ti yio si ṣubu lulẹ kú lojiji: nigbati nwọn wò titi, ti nwọn kò si ri nkankan ki o ṣe e, nwọn pa iyè da pe, oriṣa kan li ọkunrin yi.
7. Li àgbegbe ibẹ̀ ni ilẹ ọkunrin ọlọlá erekuṣu na wà, orukọ ẹniti a npè ni Publiu; ẹniti o gbà wa si ọdọ, ti o si fi inu rere mu wa wọ̀ ni ijọ mẹta.
8. O si ṣe, baba Publiu dubulẹ arùn ibà ati ọ̀rin: ẹniti Paulu wọle tọ̀ lọ, ti o si gbadura fun, nigbati o si fi ọwọ́ le e, o mu u larada.
9. Nigbati eyi si ṣe tan, awọn iyokù ti o li arùn li erekuṣu na, tọ̀ ọ wá, o si mu wọn larada: