6. Nigbati nwọn si là gbogbo erekùṣu já de Pafo, nwọn ri ọkunrin kan, oṣó, woli eke, Ju, orukọ ẹniti ijẹ Barjesu,
7. Ẹniti o wà lọdọ Sergiu Paulu bãlẹ ilu na, amoye enia. On na li o ranṣẹ pè Barnaba on Saulu, o si fẹ gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun.
8. Ṣugbọn Elima oṣó na (nitori bẹ̃ni itumọ̀ orukọ rẹ̀) o takò wọn, o nfẹ pa bãlẹ ni ọkàn da kuro ni igbagbọ́.
9. Ṣugbọn Saulu (ti a si npè ni Paulu), o kún fun Ẹmí Mimọ́, o si tẹjumọ́ ọ, o si wipe,
10. Iwọ ti o kún fun arekereke gbogbo, ati fun iwà-ìka gbogbo, iwọ ọmọ Eṣu, iwọ ọta ododo gbogbo, iwọ kì yio ha dẹkun ati ma yi ọna titọ́ Oluwa po?
11. Njẹ nisisiyi, wo o, ọwọ́ Oluwa mbẹ lara rẹ, iwọ o si fọju, iwọ kì yio ri õrùn ni sã kan. Lojukanna owusuwusu ati òkunkun si bò o; o si nwá enia kiri lati fà a lọwọ lọ.
12. Nigbati bãlẹ ri ohun ti o ṣe, o gbagbọ́, ẹnu si yà a si ẹkọ́ Oluwa.
13. Nigbati Paulu ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si ṣikọ̀ ni Pafo, nwọn wá si Perga ni Pamfilia: Johanu si fi wọn silẹ, o si pada lọ si Jerusalemu.
14. Nigbati nwọn si là Perga kọja, nwọn wá si Antioku ni Pisidia, nwọn si wọ̀ inu sinagogu li ọjọ isimi, nwọn si joko.
15. Ati lẹhin kìka iwe ofin ati iwe awọn woli, awọn olori sinagogu ranṣẹ si wọn, pe, Ará, bi ẹnyin ba li ọ̀rọ iyanju kan fun awọn enia, ẹ sọ ọ.
16. Paulu si dide duro, o si juwọ́ si wọn, o ni, Ẹnyin enia Israeli, ati ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, ẹ fi etí silẹ.