19. Nigbati o si ti run orilẹ-ède meje ni ilẹ Kenaani, o si fi ilẹ wọn fun wọn ni ini fun iwọn ãdọta-le-ni-irinwo ọdun.
20. Ati lẹhin nkan wọnyi o fi onidajọ fun wọn, titi o fi di igba Samueli woli.
21. Ati lẹhinna ni nwọn bère ọba: Ọlọrun si fun wọn ni Saulu ọmọ Kiṣi, ọkunrin kan ninu ẹ̀ya Benjamini, fun ogoji ọdún.
22. Nigbati o si mu u kuro, o gbé Dafidi dide li ọba fun wọn; ẹniti o si jẹri rẹ̀ pe, Mo ri Dafidi ọmọ Jesse ẹni bi ọkàn mi, ti yio ṣe gbogbo ifẹ mi.
23. Lati inu iru-ọmọ ọkunrin yi ni Ọlọrun ti gbe Jesu Olugbala dide fun Israeli gẹgẹ bi ileri,
24. Nigbati Johanu ti kọ́ wãsu baptismu ironupiwada fun gbogbo enia Israeli ṣaju wíwa rẹ̀.
25. Bi Johanu si ti nlà ipa tirẹ̀ já, o ni, Tali ẹnyin ṣebi emi iṣe? Emi kì iṣe on. Ṣugbọn ẹ kiyesi i, ẹnikan mbọ̀ lẹhin mi, bata ẹsẹ ẹniti emi kò to itú.
26. Ará, ẹnyin ọmọ iran Abrahamu, ati ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, awa li a rán ọ̀rọ igbala yi si.
27. Nitori awọn ti ngbe Jerusalemu, ati awọn olori wọn, nitoriti nwọn kò mọ̀ ọ, ati ọ̀rọ awọn woli, ti a nkà li ọjọjọ isimi, kò yé wọn, nwọn mu u ṣẹ ni didajọ rẹ̀ lẹbi.
28. Ati bi nwọn kò tilẹ ti ri ọ̀ran iku si i, sibẹ nwọn rọ̀ Pilatu lati pa a.
29. Bi nwọn si ti mu nkan gbogbo ṣẹ ti a ti kọwe nitori rẹ̀, nwọn si sọ ọ kalẹ kuro lori igi, nwọn si tẹ́ ẹ si ibojì.
30. Ṣugbọn Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú:
31. O si farahàn li ọjọ pipọ fun awọn ti o ba a gòke lati Galili wá si Jerusalemu, awọn ti iṣe ẹlẹri rẹ̀ nisisiyi fun awọn enia.
32. Awa si mu ihinrere wá fun nyin, ti ileri tí a ti ṣe fun awọn baba,
33. Bi Ọlọrun ti mu eyi na ṣẹ fun awọn ọmọ wa, nigbati o ji Jesu dide; bi a si ti kọwe rẹ̀ ninu Psalmu keji pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ.