7. Si wo o, angẹli Oluwa duro tì i, imọlẹ si mọ́ ninu tubu: nigbati o si lù Peteru pẹ́pẹ li ẹgbẹ o ji i, o ni, Dide kánkan. Ẹwọn rẹ̀ si bọ́ silẹ kuro lọwọ rẹ̀.
8. Angẹli na si wi fun u pe, Di àmure, ki o si so salubàta rẹ. O si ṣe bẹ̃. O si wi fun u pe, Da aṣọ rẹ bora, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.
9. On si jade, o ntọ̀ ọ lẹhin; kò si mọ̀ pe otitọ li ohun na ṣe lati ọwọ́ angẹli na wá; ṣugbọn o ṣebi on wà li ojuran.
10. Nigbati nwọn kọja iṣọ ikini ati keji, nwọn de ẹnu-ọ̀na ilẹkun irin, ti o lọ si ilu, ti o si tikararẹ̀ ṣí silẹ fun wọn: nigbati nwọn si jade, nwọn nlọ titi li ọ̀na igboro kan; lojukanna angẹli na si fi i silẹ lọ.
11. Nigbati oju Peteru si walẹ, o ni, Nigbayi ni mo to mọ̀ nitõtọ pe, Oluwa rán angẹli rẹ̀, o si gbà mi li ọwọ́ Herodu, ati gbogbo ireti awọn enia Ju.
12. Nigbati o si rò o, o lọ si ile Maria iya Johanu, ti apele rẹ̀ jẹ Marku; nibiti awọn enia pipọ pejọ si, ti nwọn ngbadura.
13. Bi o si ti kàn ilẹkun ẹnu-ọ̀na ọmọbinrin kan ti a npè ni Roda, o wá dahun.
14. Nigbati o si ti mọ̀ ohùn Peteru, kò ṣí ilẹkun fun ayọ̀, ṣugbọn o sure wọle, o si sọ pe, Peteru duro li ẹnu-ọ̀na.
15. Nwọn si wi fun u pe, Iwọ nṣiwère. Ṣugbọn o tẹnumọ́ ọ gidigidi pe Bẹ̃ni sẹ. Nwọn si wipe, Angẹli rẹ̀ ni.
16. Ṣugbọn Peteru nkànkun sibẹ, nigbati nwọn si ṣí ilẹkun, nwọn ri i, ẹnu si yà wọn.
17. Ṣugbọn o juwọ́ si wọn pe ki nwọn ki o dakẹ, o si ròhin fun wọn bi Oluwa ti mu on jade kuro ninu tubu. O si wipe, Ẹ lọ isọ nkan wọnyi fun Jakọbu, ati awọn arakunrin. Nigbati o si jade, o lọ si ibomiran.
18. Nigbati ilẹ si mọ́, èmimì diẹ kọ li o wà lãrin awọn ọmọ-ogun pe, nibo ni Peteru gbé wà.
19. Nigbati Herodu si wá a kiri, ti kò si ri i, o wádi awọn ẹ̀ṣọ, o paṣẹ pe, ki a pa wọn. O si sọkalẹ lati Judea lọ si Kesarea, o si joko nibẹ̀.
20. Herodu si mbinu gidigidi si awọn ara Tire on Sidoni: ṣugbọn nwọn fi ọkàn kan wá sọdọ rẹ̀, nigbati nwọn si ti tu Blastu iwẹfa ọba loju, nwọn mbẹbẹ fun alafia; nitori lati ilu ọba lọ li a ti mbọ́ ilu wọn.
21. Lọjọ afiyesi kan, Herodu gunwà, o joko lori itẹ́, o si nsọ̀rọ fun wọn.
22. Awọn enia si hó, wipe, Ohùn ọlọrun ni, kì si iṣe ti enia.
23. Lojukanna angẹli Oluwa lù u, nitoriti kò fi ogo fun Ọlọrun: idin si jẹ ẹ, o si kú.
24. Ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun gbilẹ, o si bi si i.