Iṣe Apo 1:14-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Gbogbo awọn wọnyi fi ọkàn kan duro si adura ati si ẹ̀bẹ, pẹlu awọn obinrin, ati Maria iya Jesu ati awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu.

15. Ni ijọ wọnni ni Peteru si dide duro li awujọ awọn ọmọ-ẹhin (iye awọn enia gbogbo ninu ijọ jẹ ọgọfa,) o ni,

16. Ẹnyin ará, Iwe-mimọ́ kò le ṣe ki o má ṣẹ, ti Ẹmi Mimọ́ ti sọtẹlẹ lati ẹnu Dafidi niti Judasi, ti o ṣe amọ̀na fun awọn ti o mu Jesu.

17. Nitori a kà a kún wa, o si ni ipin ninu iṣẹ iranṣẹ yi.

18. Njẹ ọkunrin yi sá ti fi ere aiṣõtọ rà ilẹ kan; nigbati o si ṣubu li ògedengbé, o bẹ́ li agbedemeji, gbogbo ifun rẹ̀ si tú jade.

19. O si di mimọ̀ fun gbogbo awọn ti ngbe Jerusalemu; nitorina li a fi npè igbẹ́ na ni Akeldama li ède wọn, eyini ni, Igbẹ́ ẹ̀jẹ.

20. A sá kọ ọ ninu Iwe Psalmu pe, Jẹ ki ibujoko rẹ̀ ki o di ahoro, ki ẹnikan ki o má si ṣe gbé inu rẹ̀, ati oyè rẹ̀, ni ki ẹlomiran gbà.

21. Nitorina ninu awọn ọkunrin wọnyi ti nwọn ti mba wa rìn ni gbogbo akoko ti Jesu Oluwa nwọle, ti o si njade lãrin wa,

22. Bẹ̀rẹ lati igba baptismu Johanu wá, titi o fi di ọjọ na ti a gbé e lọ soke kuro lọdọ wa, o yẹ ki ọkan ninu awọn wọnyi ṣe ẹlẹri ajinde rẹ̀ pẹlu wa.

23. Nwọn si yàn awọn meji, Josefu ti a npè ni Barsabba, ẹniti a sọ apele rẹ̀ ni Justu, ati Mattia.

24. Nwọn si gbadura, nwọn si wipe, Iwọ, Oluwa, olumọ̀ ọkàn gbogbo enia, fihàn ninu awọn meji yi, ewo ni iwọ yàn,

25. Ki o le gbà ipò ninu iṣẹ iranṣẹ yi ati iṣẹ aposteli, eyiti Judasi ṣubu kuro ninu rẹ̀ ki o le lọ si ipò ti ara rẹ̀.

26. Nwọn si dìbo fun wọn; ìbo si mu Mattia; a si kà a mọ awọn aposteli mọkanla.

Iṣe Apo 1