6. Ilẹ Egipti ni yi niwaju rẹ; ninu ãyo ilẹ ni ki o mu baba ati awọn arakunrin rẹ joko; jẹ ki nwọn ki o joko ni ilẹ Goṣeni: bi iwọ ba si mọ̀ ẹnikẹni ti o li ãpọn ninu wọn, njẹ ki iwọ ki o ṣe wọn li olori lori ẹran-ọsin mi.
7. Josefu si mú Jakobu baba rẹ̀ wọle wá, o si mu u duro niwaju Farao: Jakobu si sure fun Farao.
8. Farao si bi Jakobu pe, Ọdún melo li ọjọ́ aiye rẹ?
9. Jakobu si wi fun Farao pe, Ãdoje ọdún li ọjọ́ atipo mi: diẹ ti on ti buburu li ọdún ọjọ́ aiye mi jẹ́, nwọn kò si ti idé ọdún ọjọ́ aiye awọn baba mi li ọjọ́ atipo wọn.
10. Jakobu si sure fun Farao, o si jade kuro niwaju Farao.
11. Josefu si fi baba rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ joko, o si fun wọn ni iní ni ilẹ Egipti, ni ibi ãyo ilẹ, ni ilẹ Ramesesi, bi Farao ti pa li aṣẹ.
12. Josefu si fi onjẹ bọ́ baba rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo ile baba rẹ̀ gẹgẹ bi iye awọn ọmọ wọn.
13. Onjẹ kò si sí ni gbogbo ilẹ; nitori ti ìyan na mú gidigidi, tobẹ̃ ti ilẹ Egipti ati gbogbo ilẹ Kenaani gbẹ nitori ìyan na.
14. Josefu si kó gbogbo owo ti a ri ni ilẹ Egipti ati ni ilẹ Kenaani jọ, fun ọkà ti nwọn rà: Josefu si kó owo na wá si ile Farao.
15. Nigbati owo si tán ni ilẹ Egipti, ati ni ilẹ Kenaani, gbogbo awọn ara Egipti tọ̀ Josefu wá, nwọn si wipe, Fun wa li onjẹ: nitori kili awa o ṣe kú li oju rẹ? owo sa tán.
16. Josefu si wipe, Ẹ mú ẹran nyin wá, emi o si fun nyin li onjẹ dipò ẹran nyin, bi owo ba tán.
17. Nwọn si mú ẹran wọn tọ̀ Josefu wá: Josefu si fun wọn li onjẹ dipò ẹṣin, ati ọwọ́-ẹran, ati dipò ọwọ́-malu, ati kẹtẹkẹtẹ: o si fi onjẹ bọ́ wọn dipò gbogbo ẹran wọn li ọdún na.
18. Nigbati ọdún na si pari, nwọn si tọ̀ ọ wá li ọdún keji, nwọn si wi fun u pe, Awa ki yio pa a mọ́ lọdọ oluwa mi, bi a ti ná owo wa tán; ẹran-ọ̀sin si ti di ti oluwa mi; kò si sí nkan ti o kù li oju oluwa mi, bikoṣe ara wa, ati ilẹ wa:
19. Nitori kili awa o ṣe kú li oju rẹ, ati awa ati ilẹ wa? fi onjẹ rà wa ati ilẹ wa, ati awa ati ilẹ wa yio ma ṣe ẹrú Farao: ki o si fun wa ni irugbìn, ki awa ki o le yè, ki a má kú, ki ilẹ ki o má ṣe di ahoro.