Gẹn 31:36-50 Yorùbá Bibeli (YCE)

36. Inu si bi Jakobu, o si bá Labani sọ̀: Jakobu si dahùn o wi fun Labani pe, Kini irekọja mi? kili ẹ̀ṣẹ mi ti iwọ fi lepa mi wìriwiri bẹ̃?

37. Njẹ bi iwọ ti tú ẹrù mi gbogbo, kili iwọ ri ninu gbogbo nkan ile rẹ? gbé e kalẹ nihinyi niwaju awọn arakunrin rẹ, ki nwọn ki o le ṣe idajọ rẹ̀ fun awa mejeji.

38. Ogún ọdún yi ni mo ti wà lọdọ rẹ; agutan rẹ ati ewurẹ rẹ kò sọnù, agbo ọwọ́-ẹran rẹ li emi kò si pajẹ.

39. Eyiti ẹranko fàya emi kò mú u fun ọ wá; emi li o gbà òfo rẹ̀; li ọwọ́ mi ni iwọ bère rẹ̀, a ba jí i li ọsán, a ba jí i li oru.

40. Bayi ni mo wà; ongbẹ ngbẹ mi li ọsán, otutù si nmu mi li oru: orun mi si dá kuro li oju mi.

41. Bayi li o ri fun mi li ogún ọdún ni ile rẹ; mo sìn ọ li ọdún mẹrinla nitori awọn ọmọbinrin rẹ mejeji, ati li ọdún mẹfa nitori ohun-ọ̀sin rẹ: iwọ si pa ọ̀ya mi dà nigba mẹwa.

42. Bikoṣe bi Ọlọrun baba mi, Ọlọrun Abrahamu, ati ẹ̀ru Isaaki ti wà pẹlu mi, nitõtọ ofo ni iwọ iba rán mi jade lọ. Ọlọrun ri ipọnju mi, ati lãla ọwọ́ mi, o si ba ọ wi li oru aná.

43. Labani si dahùn o si wi fun Jakobu pe, Awọn ọmọbinrin wọnyi, awọn ọmọbinrin mi ni, ati awọn ọmọ wọnyi, awọn ọmọ mi ni, ati awọn ọwọ́-ẹran wọnyi ọwọ́-ẹran mi ni, ati ohun gbogbo ti o ri ti emi ni: kili emi iba si ṣe si awọn ọmọbinrin mi wọnyi loni, tabi si awọn ọmọ wọn ti nwọn bí?

44. Njẹ nisisiyi, wá, jẹ ki a bá ara wa dá majẹmu, temi tirẹ; ki o si ṣe ẹrí lãrin temi tirẹ.

45. Jakobu si mú okuta kan, o si gbé e ró ṣe ọwọ̀n.

46. Jakobu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ ma kó okuta jọ; nwọn si kó okuta jọ, nwọn si ṣe òkiti: nwọn si jẹun nibẹ̀ lori òkiti na.

47. Labani si sọ orukọ rẹ̀ ni Jegari-Sahaduta: ṣugbọn Jakobu sọ ọ ni Galeedi.

48. Labani si wipe, Òkiti yi li ẹri lãrin temi tirẹ loni. Nitori na li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Galeedi:

49. Ati Mispa; nitori ti o wipe, Ki OLUWA ki o ma ṣọ́ temi tirẹ nigbati a o yà kuro lọdọ ara wa.

50. Bi iwọ ba pọ́n awọn ọmọbinrin mi li oju, tabi bi iwọ ba fẹ́ aya miran pẹlu awọn ọmọbinrin mi, kò sí ẹnikan pẹlu wa; wò o, Ọlọrun li ẹlẹri lãrin temi tirẹ.

Gẹn 31