11. O si wi pe, Tali o wi fun ọ pe iwọ wà ni ìhoho? iwọ ha jẹ ninu igi nì, ninu eyiti mo paṣẹ fun ọ pe iwọ kò gbọdọ jẹ?
12. Ọkunrin na si wipe, Obinrin ti iwọ fi pẹlu mi, on li o fun mi ninu eso igi na, emi si jẹ.
13. OLUWA Ọlọrun si bi obinrin na pe, Ewo ni iwọ ṣe yi? Obinrin na si wipe, Ejò li o tàn mi, mo si jẹ.
14. OLUWA Ọlọrun si wi fun ejò na pe, nitori ti iwọ ti ṣe eyi, a fi iwọ bú ninu gbogbo ẹran ati ninu gbogbo ẹranko igbẹ; inu rẹ ni iwọ o ma fi wọ́, erupẹ ilẹ ni iwọ o ma jẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo.
15. Emi o si fi ọta sãrin iwọ ati obinrin na, ati sãrin irú-ọmọ rẹ ati irú-ọmọ rẹ̀: on o fọ́ ọ li ori, iwọ o si pa a ni gigĩsẹ.
16. Fun obinrin na li o wipe, Emi o sọ ipọnju ati iloyun rẹ di pupọ̀; ni ipọnju ni iwọ o ma bimọ; lọdọ ọkọ rẹ ni ifẹ rẹ yio ma fà si, on ni yio si ma ṣe olori rẹ.
17. O si wi fun Adamu pe, Nitoriti iwọ gbà ohùn aya rẹ gbọ́, ti iwọ si jẹ ninu eso igi na, ninu eyiti mo ti paṣẹ fun ọ pe, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀; a fi ilẹ bú nitori rẹ; ni ipọnju ni iwọ o ma jẹ ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo;
18. Ẹgún on oṣuṣu ni yio ma hù jade fun ọ, iwọ o si ma jẹ eweko igbẹ:
19. Li õgùn oju rẹ ni iwọ o ma jẹun, titi iwọ o fi pada si ilẹ; nitori inu rẹ̀ li a ti mu ọ wá, erupẹ sa ni iwọ, iwọ o si pada di erupẹ.
20. Adamu si pè orukọ aya rẹ̀ ni Efa; nitori on ni iṣe iya alãye gbogbo.
21. Ati fun Adamu ati fun aya rẹ̀ li OLUWA Ọlọrun da ẹwu awọ, o si fi wọ̀ wọn.