2. O si wipe, Wò o na, emi di arugbo, emi kò si mọ̀ ọjọ́ ikú mi;
3. Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ohun ọdẹ rẹ, apó rẹ, ati ọrun rẹ, ki o si jade lọ si igbẹ́ ki o si pa ẹran-igbẹ́ fun mi wá:
4. Ki o si sè ẹran adidùn fun mi, bi irú eyiti mo fẹ́, ki o si gbé e tọ̀ mi wá, ki emi ki o jẹ: ki ọkàn mi ki o súre fun ọ ki emi to kú.
5. Rebeka si gbọ́ nigbati Isaaki nwi fun Esau, ọmọ rẹ̀. Esau si lọ si igbẹ́ lọ iṣọdẹ, lati pa ẹran-igbẹ́ wá.
6. Rebeka si wi fun Jakobu ọmọ rẹ̀ pe, Wò o, mo gbọ́ baba rẹ wi fun Esau arakunrin rẹ pe,
7. Mu ẹran-igbẹ́ fun mi wá, ki o si sè ẹran adidùn fun mi, ki emi ki o jẹ, ki emi ki o sure fun ọ niwaju OLUWA ṣaju ikú mi.
8. Njẹ nisisiyi, ọmọ mi, gbọ́ ohùn mi, gẹgẹ bi emi o ti paṣẹ fun ọ.
9. Lọ nisisiyi sinu agbo-ẹran, ki o si mu ọmọ ewurẹ meji daradara fun mi lati ibẹ̀ wá: emi o si sè wọn li ẹran adidùn fun baba rẹ, bi irú eyiti o fẹ́:
10. Iwọ o si gbé e tọ̀ baba rẹ lọ, ki o le jẹ, ki o le súre fun ọ, ki on to kú.
11. Jakobu si wi fun Rebeka iya rẹ̀ pe, Kiyesi i, enia onirun ni Esau arakunrin mi, alara ọbọrọ́ si li emi:
12. Bọya baba mi yio fọwọbà mi, emi o si dabi ẹlẹ̀tan fun u; emi o si mu egún wá si ori mi ki yio ṣe ibukún.
13. Iya rẹ̀ si wi fun u pe, lori mi ni ki egún rẹ wà, ọmọ mi: sá gbọ́ ohùn mi, ki o si lọ mu wọn fun mi wá.
14. O si lọ, o mu wọn, o si fà wọn tọ̀ iya rẹ̀ wá: iya rẹ̀ si sè ẹran adidùn; bi irú eyiti baba rẹ̀ fẹ́.
15. Rebeka si mu ãyo aṣọ Esau, ọmọ rẹ̀ ẹgbọ́n, ti o wà lọdọ rẹ̀ ni ile, o si fi wọn wọ̀ Jakobu, ọmọ rẹ̀ aburo:
16. O si fi awọ awọn ọmọ ewurẹ wọnni bò o li ọwọ́, ati si ọbọrọ́ ọrùn rẹ̀:
17. O si fi ẹran adidùn na, ati àkara ti o ti pèse, le Jakobu, ọmọ rẹ̀, lọwọ.
18. O si tọ̀ baba rẹ̀ wá, o wipe, Baba mi: on si wipe, Emi niyi; iwọ tani nì ọmọ mi?