Gẹn 21:5-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Abrahamu si jẹ ẹni ọgọrun ọdún, nigbati a bí Isaaki ọmọ rẹ̀ fun u.

6. Sara si wipe, Ọlọrun pa mi lẹrin; gbogbo ẹniti o gbọ́ yio si rẹrin pẹlu mi.

7. O si wipe, Tani iba wi fun Abrahamu pe, Sara yio fi ọmú fun ọmọ mu? mo sá bí ọmọ kan fun u li ogbologbo rẹ̀.

8. Ọmọ na si dàgba, a si já a li ẹnu ọmú: Abrahamu si sè àse nla li ọjọ́ na ti a já Isaaki li ẹnu ọmú.

9. Sara si ri ọmọ Hagari, ara Egipti, ti o bí fun Abrahamu, o nfi i rẹrin.

10. Nitorina li o ṣe wi fun Abrahamu pe, Lé ẹrubirin yi jade ti on ti ọmọ rẹ̀: nitoriti ọmọ ẹrubirin yi ki yio ṣe arole pẹlu Isaaki, ọmọ mi.

11. Ọrọ yi si buru gidigidi li oju Abrahamu nitori ọmọ rẹ̀.

12. Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Máṣe jẹ ki o buru li oju rẹ nitori ọmọdekunrin na, ati nitori ẹrubirin rẹ; ni gbogbo eyiti Sara sọ fun ọ, fetisi ohùn rẹ̀; nitori ninu Isaaki li a o ti pè irú-ọmọ rẹ.

13. Ati ọmọ ẹrubirin na pẹlu li emi o sọ di orilẹ-ède, nitori irú-ọmọ rẹ ni iṣe.

14. Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o mu àkara ati ìgo omi kan, o fi fun Hagari, o gbé e lé e li ejika, ati ọmọ na, o si lé e jade: on si lọ, o nrìn kakiri ni ijù Beer-ṣeba.

15. Omi na si tán ninu ìgo, o si sọ̀ ọmọ na si abẹ ìgboro kan.

16. O si lọ, o joko kọju si i, li ọ̀na jijìn rére, o tó bi itafasi kan: nitori ti o wipe, Ki emi má ri ikú ọmọ na. O si joko kọju si i, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o nsọkun.

17. Ọlọrun si gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na: angeli Ọlọrun si pè Hagari lati ọrun wá, o bi i pe, Kili o ṣe ọ, Hagari? máṣe bẹ̀ru; nitori ti Ọlọrun ti gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na nibiti o gbé wà.

18. Dide, gbé ọmọdekunrin na, ki o si dì i mu; nitori ti emi o sọ ọ di orilẹ-ède nla.

19. Ọlọrun si ṣí i li oju, o si ri kanga omi kan; o lọ, o si pọnmi kún ìgo na, o si fi fun ọmọdekunrin na mu.

20. Ọlọrun si wà pẹlu ọmọdekunrin na; o si dàgba, o si joko ni ijù, o di tafatafa.

Gẹn 21