Gẹn 13:10-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Loti si gboju rẹ̀ si oke, o si wò gbogbo àgbegbe Jordani, pe o li omi nibi gbogbo, ki OLUWA ki o to pa Sodomu on Gomorra run, bi ọgbà OLUWA, bi ilẹ Egipti, bi iwọ ti mbọ̀wa si Soari.

11. Nigbana ni Loti yàn gbogbo àgbegbe Jordani fun ara rẹ̀; Loti si nrìn lọ si ìha ìla-õrùn: bẹ̃ni nwọn yà ara wọn, ekini kuro lọdọ ekeji.

12. Abramu si joko ni ilẹ Kenaani, Loti si joko ni ilu àgbegbe nì, o si pagọ́ rẹ̀ titi de Sodomu.

13. Ṣugbọn awọn ọkunrin Sodomu ṣe enia buburu, ati ẹlẹṣẹ gidigidi niwaju OLUWA.

14. OLUWA si wi fun Abramu, lẹhin igbati Loti yà kuro lọdọ rẹ̀ tan pe, Gbé oju rẹ soke nisisiyi, ki o si wò lati ibi ti o gbé wà nì lọ, si ìha ariwa, ati si ìha gusu, si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ìwọ-õrùn:

15. Gbogbo ilẹ ti o ri nì, iwọ li emi o sa fi fun ati fun irú-ọmọ rẹ lailai.

16. Emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi erupẹ ilẹ: tobẹ̃ bi o ba ṣepe enia kan ba le kà iye erupẹ ilẹ, on li a o to le kaye irú-ọmọ rẹ pẹlu.

17. Dide, rìn ilẹ na já ni ìna rẹ̀, ati ni ibú rẹ̀; nitori iwọ li emi o fi fun.

18. Nigbana ni Abramu ṣí agọ́ rẹ̀, o si wá o si joko ni igbo Mamre, ti o wà ni Hebroni, o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA.

Gẹn 13