Nigbana ni Loti yàn gbogbo àgbegbe Jordani fun ara rẹ̀; Loti si nrìn lọ si ìha ìla-õrùn: bẹ̃ni nwọn yà ara wọn, ekini kuro lọdọ ekeji.