Tẹsalonika Keji 2:8-12 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Nígbà tí ó bá kúrò lọ́nà tán ni Ọkunrin Burúkú nnì yóo wá farahàn. Ṣugbọn Oluwa Jesu yóo fi èémí ẹnu rẹ̀ pa á, yóo sọ ìfarahàn rẹ̀ di asán.

9. Nítorí Ẹni Burúkú yìí yóo farahàn pẹlu agbára Èṣù: yóo máa pidán, yóo ṣe iṣẹ́ àmì, yóo ṣe iṣẹ́ ìtànjẹ tí ó yani lẹ́nu.

10. Yóo fi ọ̀nà àrékérekè burúkú lóríṣìíríṣìí tan àwọn ẹni ègbé jẹ, nítorí wọn kò ní ìfẹ́ òtítọ́, tí wọn ìbá fi rí ìgbàlà.

11. Nítorí èyí, Ọlọrun rán agbára ìtànjẹ sí wọn, kí wọ́n lè gba èké gbọ́,

12. kí gbogbo àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́ lè gba ìdálẹ́bi, àní, àwọn tí wọ́n ní inú dídùn sí ìwà ibi.

Tẹsalonika Keji 2