5. Lẹ́yìn náà, ọkàn Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí dá a lẹ́bi nítorí pé ó gé etí aṣọ Saulu.
6. Ó sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Kí OLUWA pa mí mọ́ kúrò ninu ṣíṣe ibi sí oluwa mi, ẹni tí OLUWA ti yàn gẹ́gẹ́ bí ọba. N kò gbọdọ̀ fọwọ́ mi kàn án, nítorí ẹni àmì òróró OLUWA ni.”
7. Nípa báyìí Dafidi dá àwọn eniyan rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọ́n pa Saulu.Saulu jáde ninu ihò náà, ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.
8. Dafidi jáde, ó pè é, ó ní, “Olúwa mi ọba,” bí Saulu ti wo ẹ̀yìn ni Dafidi dojúbolẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún un.
9. Ó sọ fún un pé, “Kí ló dé tí o fi ń gbọ́ ti àwọn tí wọ́n ń sọ pé mo fẹ́ pa ọ́?
10. Nisinsinyii, o rí i dájú pé OLUWA fi ọ́ lé mi lọ́wọ́ ninu ihò àpáta. Àwọn kan ninu àwọn ọkunrin mi rọ̀ mí pé kí n pa ọ́, ṣugbọn mo kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Mo sọ fún wọn pé, n kò ní fọwọ́ mi kàn ọ́, nítorí pé ẹni àmì òróró OLUWA ni ọ́.
11. Wò ó! Baba mi, wo etí aṣọ rẹ tí mo mú lọ́wọ́ yìí, ǹ bá pa ọ́ bí mo bá fẹ́, ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, mo gé etí aṣọ rẹ. Ó yẹ kí èyí fihàn ọ́ pé n kò ní ìfẹ́ láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ, tabi láti pa ọ́. Ṣugbọn ìwọ ń lé mi kiri láti pa mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ṣe ọ́ níbi.
12. Kí OLUWA dájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ. Kí ó sì jẹ ọ́ níyà fún ìwà burúkú tí ò ń hù sí mi, nítorí pé n kò ní ṣe ọ́ ní ibi kan.