Samuẹli Kinni 2:15-24 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ati pé, kí wọ́n tilẹ̀ tó rẹ́ ọ̀rá tí wọ́n máa ń sun kúrò lára ẹran, iranṣẹ alufaa á wá, a sì wí fún ẹni tí ń rú ẹbọ pé kí ó fún òun ninu ẹran tí alufaa yóo sun jẹ, nítorí pé alufaa kò ní gba ẹran bíbọ̀ lọ́wọ́ olúwarẹ̀, àfi ẹran tútù.

16. Bí ẹni tí ń rú ẹbọ náà bá dá a lóhùn pé “Jẹ́ kí á kọ́kọ́ sun ọ̀rá ẹran náà, lẹ́yìn náà kí o wá mú ohun tí ó bá wù ọ́.” Iranṣẹ alufaa náà á wí pé, “Rárá! Nisinsinyii ni kí o fún mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo mú un tipátipá.”

17. Ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn ọmọ Eli ń dá yìí burú pupọ lójú OLUWA, nítorí pé wọn kò náání ẹbọ OLUWA.

18. Ní gbogbo àkókò yìí, Samuẹli ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA, ó sì jẹ́ ọmọde nígbà náà, a máa wọ ẹ̀wù efodu funfun.

19. Ní ọdọọdún ni ìyá rẹ̀ máa ń dá ẹ̀wù kékeré, a sì mú un lọ́wọ́ lọ fún un, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ lọ, láti lọ rúbọ.

20. Eli a máa súre fún Elikana ati Hana aya rẹ̀ pé, “OLUWA yóo jẹ́ kí obinrin yìí bí ọmọ mìíràn fún ọ, dípò èyí tí ó yà sọ́tọ̀ fún OLUWA.”Lẹ́yìn náà, wọn yóo pada lọ sí ilé wọn.

21. OLUWA bukun Hana: ọmọkunrin mẹta, ati ọmọbinrin meji ni ó tún bí lẹ́yìn Samuẹli. Samuẹli sì ń dàgbà níbi tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA.

22. Eli ti di arúgbó gan-an ní àkókò yìí. Ó ń gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli, ati bí wọ́n ti ṣe ń bá àwọn obinrin tí wọn ń ṣiṣẹ́ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ lòpọ̀.

23. A máa bi wọ́n léèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe báyìí? Gbogbo ìwà burúkú tí ẹ̀ ń hù sí àwọn eniyan ni mò ń gbọ́.

24. Ẹ̀yin ọmọ mi, ọ̀rọ̀ burúkú ni àwọn eniyan OLUWA ń sọ káàkiri nípa yín.

Samuẹli Kinni 2