1. Lẹ́yìn tí Dafidi ati Saulu parí ọ̀rọ̀ wọn, ọkàn Jonatani, ọmọ Saulu fà mọ́ Dafidi lọpọlọpọ ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ara rẹ̀.
2. Saulu gba Dafidi sọ́dọ̀ ní ọjọ́ náà, kò sì jẹ́ kí ó pada sílé baba rẹ̀.
3. Jonatani bá bá Dafidi dá majẹmu, nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ara rẹ̀.
4. Ó bọ́ aṣọ tí ó wọ̀ fún Dafidi, ó sì kó ihamọra rẹ̀ pẹlu idà ati ọfà ati àmùrè rẹ̀ fún un.
5. Dafidi ń ṣe àṣeyọrí ninu àwọn iṣẹ́ tí Saulu ń rán an. Nítorí náà, Saulu fi ṣe ọ̀kan ninu àwọn olórí ogun rẹ̀. Èyí sì tẹ́ àwọn olórí yòókù lọ́rùn.
6. Bí wọ́n ti ń pada bọ̀ wálé, lẹ́yìn tí Dafidi ti pa Goliati, àwọn obinrin jáde láti gbogbo ìlú Israẹli, wọ́n lọ pàdé Saulu ọba, pẹlu orin ati ijó, wọ́n ń lu aro, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀ pẹlu àwọn ohun èlò orin.
7. Bí wọ́n ti ń jó, wọ́n ń kọrin báyìí pé,“Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀,ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀.”
8. Inú Saulu kò dùn sí orin tí wọ́n ń kọ, inú sì bí i gidigidi. Ó ní, “Wọ́n fún Dafidi ní ẹgbẹẹgbaarun ṣugbọn wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹrun, kí ló kù tí wọn óo fún un ju ìjọba mi lọ.”
9. Láti ọjọ́ náà ni Saulu ti ń ṣe ìlara Dafidi.
10. Ní ọjọ́ keji, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bà lé Saulu, ó sì ń sọ kántankàntan láàrin ilé rẹ̀. Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí ta hapu fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ọ̀kọ̀ kan wà lọ́wọ́ Saulu.
11. Ó ju ọ̀kọ̀ náà, ó ní kí òun fi gún Dafidi ní àgúnmọ́ ògiri. Ó ju ọ̀kọ̀ náà nígbà meji, ṣugbọn Dafidi yẹ̀ ẹ́ lẹẹmejeeji.