Samuẹli Kinni 11:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Saulu bá kó wọn jọ ní Beseki. Ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) ni àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli, àwọn tí wọ́n wá láti Juda sì jẹ́ ẹgbaa mẹẹdogun (30,000).

9. Wọ́n sọ fún àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wá láti Jabeṣi-Gileadi pé, “Ẹ sọ fún àwọn eniyan yín pé, ní ọ̀sán ọ̀la, a óo gbà wọ́n kalẹ̀.” Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi gbọ́ ìròyìn náà, inú wọn dùn gidigidi.

10. Wọ́n wí fún Nahaṣi pé, “Lọ́la ni a óo jọ̀wọ́ ara wa fún ọ, ohunkohun tí ó bá sì wù ọ́ ni o lè fi wá ṣe.”

11. Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Saulu pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí ọ̀nà mẹta, wọ́n kọlu ibùdó àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n títí di ọ̀sán ọjọ́ náà. Àwọn tí kò kú lára wọn fọ́nká, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi sí eniyan meji tí wọ́n dúró papọ̀.

12. Àwọn ọmọ Israẹli bá bèèrè lọ́wọ́ Samuẹli pé, “Níbo ni àwọn tí wọ́n sọ pé kò yẹ kí Saulu jẹ ọba wa wà? Ẹ kó wọn jáde, kí á pa wọ́n.”

13. Ṣugbọn Saulu dá wọn lóhùn pé, “A kò ní pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí pé, òní ni ọjọ́ tí OLUWA gba Israẹli là.”

Samuẹli Kinni 11