Samuẹli Keji 14:6-10 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ọmọkunrin meji ni mo bí. Ní ọjọ́ kan, àwọn mejeeji ń bá ara wọn jà ninu pápá, kò sì sí ẹnikẹ́ni nítòsí láti là wọ́n, ni ọ̀kan ninu wọn bá lu ekeji rẹ̀ pa.

7. Nisinsinyii, kabiyesi, gbogbo àwọn eniyan mi ni wọ́n ti kẹ̀yìn sí mi. Wọ́n ní dandan kí ń fa ọmọ mi kan yòókù kalẹ̀ fún àwọn, kí wọ́n lè pa á nítorí arakunrin rẹ̀ tí ó pa. Bí mo bá gbà fún wọn, kò ní sí ẹni tí yóo jogún ọkọ mi, wọn yóo já ìrètí mi kan tí ó kù kulẹ̀, kò sì ní sí ọmọkunrin tí yóo gbé orúkọ ọkọ mi ró, tí orúkọ náà kò fi ní parun.”

8. Ọba dá a lóhùn pé, “Máa pada lọ sí ilé rẹ, n óo mójú tó ọ̀rọ̀ náà.”

9. Obinrin náà wí fún ọba pé, “Kabiyesi, gbogbo ohun tí o bá ṣe nípa ọ̀rọ̀ yìí, èmi ati ìdílé mi ni a ni ẹ̀bi rẹ̀, ẹ̀bi rẹ̀ kò kan kabiyesi ati ìdílé rẹ̀ rárá.”

10. Ọba dá a lóhùn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá tún halẹ̀ mọ́ ọ, mú olúwarẹ̀ wá sọ́dọ̀ mi, kò sì ní dé ọ̀dọ̀ rẹ mọ́ laelae.”

Samuẹli Keji 14