22. Dafidi dá wọn lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí ó wà láàyè, mo gbààwẹ̀, mo sì sọkún, pé bóyá OLUWA yóo ṣàánú mi, kí ó má kú.
23. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti kú, kí ni n óo tún máa gbààwẹ̀ sí? Ṣé mo lè jí i dìde ni? Èmi ni n óo tọ̀ ọ́ lọ, kò tún lè pada tọ̀ mí wá mọ́.”
24. Dafidi bá tu Batiṣeba, aya rẹ̀ ninu, ó bá a lòpọ̀, ó sì bí ọmọkunrin kan fún un. Dafidi sọ ọmọ yìí ní Solomoni. OLUWA fẹ́ràn ọmọ náà,
25. ó sì rán Natani wolii pé kí ó sọ ọmọ náà ní Jedidaya, nítorí pé, OLUWA fẹ́ràn rẹ̀.
26. Ní gbogbo àkókò yìí, Joabu wà níbi tí ó ti gbógun ti Raba, olú ìlú àwọn ará Amoni, ó sì gba ìlú ọba wọn.