Samuẹli Keji 11:4-11 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Dafidi bá ranṣẹ lọ pè é. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bá a lòpọ̀. Batiṣeba sì ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ètò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tí ó parí nǹkan oṣù rẹ̀ ni. Ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀.

5. Nígbà tí ó yá, ó rí i pé òun lóyún, ó sì rán oníṣẹ́, pé kí wọ́n sọ fún Dafidi ọba.

6. Dafidi bá ranṣẹ sí Joabu, pé kí ó fi Uraya ará Hiti ranṣẹ sí òun, Joabu sì fi ranṣẹ sí Dafidi.

7. Nígbà tí Uraya dé, Dafidi bèèrè alaafia Joabu ati ti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó bèèrè bí ogun ti ń lọ sí.

8. Lẹ́yìn náà, ó wí fún Uraya pé, “Máa lọ sí ilé rẹ kí o sì sinmi fún ìgbà díẹ̀.” Uraya kúrò lọ́dọ̀ ọba, Dafidi sì di ẹ̀bùn ranṣẹ sí i.

9. Ṣugbọn Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀, ó sùn sí ẹnu ọ̀nà ààfin pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba tí ń ṣọ́ ààfin.

10. Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “O ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ìrìn àjò dé ni, kí ló dé tí o kò lọ sí ilé rẹ?”

11. Uraya dá a lóhùn pé, “Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Juda wà lójú ogun, àpótí ẹ̀rí OLUWA sì wà pẹlu wọn. Joabu balogun mi ati àwọn ọ̀gágun wà lójú ogun, níbi tí wọ́n pàgọ́ sí ní ìta gbangba, ṣé ó yẹ kí n lọ sílé, kí n máa jẹ, kí n máa mu, kí n sì sùn ti aya mi? Níwọ̀n ìgbà tí o wà láyé, tí o sì wà láàyè, n kò jẹ́ dán irú rẹ̀ wò.”

Samuẹli Keji 11