1. Ẹsẹ̀ rẹ ti dára tó ninu bàtà,ìwọ, ọmọ aládé.Itan rẹ dàbí ohun ọ̀ṣọ́,tí ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà ṣe.
2. Ìdodo rẹ dàbí abọ́,tí kì í gbẹ fún àdàlú waini,ikùn rẹ dàbí òkítì ọkà,tí a fi òdòdó lílì yíká.
3. Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji,tí wọn jẹ́ ìbejì.
4. Ọrùn rẹ dàbí ilé-ìṣọ́ tí wọn fi eyín erin kọ́.Ojú rẹ dàbí adágún omi ìlú Heṣiboni,tí ó wà ní ẹnubodè Batirabimu.Imú rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Lẹbanoni,tí ó dojú kọ ìlú Damasku.
5. Orí rẹ dàbí adé lára rẹ, ó rí bí òkè Kamẹli,irun rẹ dàbí aṣọ elése-àlùkò tí ó ṣẹ́ léra, wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́irun orí rẹ ń dá ọba lọ́rùn.
6. O dára, o wuni gan-an,olùfẹ́ mi, ẹlẹgẹ́ obinrin.
7. Ìdúró rẹ dàbí igi ọ̀pẹ,ọyàn rẹ ṣù bí ìdì èso àjàrà.
8. Mo ní n óo gun ọ̀pẹ ọ̀hún,kí n di odi rẹ̀ mú.Kí ọmú rẹ dàbí ìdì èso àjàrà,kí èémí ẹnu rẹ rí bí òórùn èso ápù.
9. Ìfẹnukonu rẹ dàbí ọtí waini tí ó dára jùlọ,tí ń yọ́ lọ lọ́nà ọ̀fun,tí ń yọ́ lọ láàrin ètè ati eyín.
10. Olùfẹ́ mi ló ni mí,èmi ni ọkàn rẹ̀ sì fẹ́.