Orin Solomoni 4:11-15 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Oyin ní ń kán ní ètè rẹ, iyawo mi,wàrà ati oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ,òórùn dídùn aṣọ rẹ dàbí òórùn Lẹbanoni.

12. Arabinrin mi dàbí ọgbà tí a ti ti ìlẹ̀kùn rẹ̀.Ọgbà tí a tì ni iyawo mi;àní orísun omi tí a tì ni ọ́.

13. Àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ tí ń sọ dàbí ọgbà pomegiranate,tí ó kún fún èso tí ó dára jùlọ,àwọn bíi igi hena ati nadi;

14. igi nadi ati Safironi, Kalamusi ati Sinamoni,pẹlu oríṣìíríṣìí igi turari,igi òjíá, ati ti aloe,ati àwọn ojúlówó turari tí òórùn wọn dára jùlọ.

15. Ọgbà tí ó ní orísun omi ni ọ́,kànga omi tútù,àní, odò tí ń ṣàn, láti òkè Lẹbanoni.

Orin Solomoni 4